Nitori aabọ owo-osu t’Akeredolu n san fawọn oṣiṣẹ, awọn dokita bẹrẹ iyansẹlodi l’Ondo 

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ẹgbẹ awọn dokita to n ṣiṣẹ nileewosan ijọba nipinlẹ Ondo ti bẹrẹ iyansẹlodi ọlọjọ gbọọrọ latari aabọ owo-osu ti Gomina Rotimi Akeredolu san fawọn oṣiṣẹ.

Alukoro ẹgbẹ ọhun nipinlẹ Ondo, Dokita Ọmọlayọ Olubọsẹde, to gba ẹnu awọn ẹgbẹ rẹ sọrọ ni awọn ti pasẹ fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ awọn to n ṣiṣẹ nileewosan ẹkọsẹ iṣegun fasiti imọ iṣegun to wa niluu Ondo ati gbogbo awọn to n tọju eyin lati maa wo iṣẹ niran titi tijọba yoo fi ṣe ohun ti awọn n beere fun.

Olubọsẹde ni awọn ko fara mọ aabọ owo-osu kọkanla, ọdun to kọja, tijọba Rotimi Akeredolu ṣẹṣẹ n san fawọn oṣiṣẹ ninu oṣu keji, ọdun ta a wa yii.

O ni o dọjọ ti wọn ba san gbogbo ajẹsilẹ owo-osu tijọba jẹ awọn pe perepere kawọn too tun pada sẹnu isẹ.

Ọpọlọpọ awọn osisẹ ipinlẹ Ondo ni wọn fi aidunnu wọn han si ọna ti Akeredolu fi n sanwo oṣu fun wọn lati ọdun to kọja.

Ohun ti gomina ọhun tẹnumọ lasiko to n polongo ibo ni pe oun ko ni i jẹ awọn oṣiṣẹ lowo-osu rara, ó ni nnkan akọkọ ti yoo jẹ ijọba oun logun ju lọ ni sisan owo-osu awọn oṣiṣẹ deedee.

Aketi si mu ileri rẹ ṣẹ loootọ pẹlu bo ṣe n sanwo ọhun deedee fun bii ọdun mẹta to kọkọ dori ipo, koda kiakia lo sare san owo oṣu mẹfa ninu meje ti ijọba Dokita Olusẹgun Mimiko jẹ silẹ ko too lọ.

Inu oṣu keji, ọdun to kọja, ni nnkan bẹrẹ si i daru diẹdiẹ mọ gomina ọhun lọwọ pẹlu bo ṣe bẹrẹ si i san aabọ owo-osu fawọn olukọ ileewe alakọọbẹrẹ atawọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ nigba tawọn yooku si n ri tiwọn gba pe, bo tilẹ jẹ pe sisan rẹ ko lọ deede mọ bii tí atẹyinwa.

Ohun to ya gbogbo awọn osisẹ ipinlẹ Ondo lẹnu ni bi Akeredolu ṣe san ida aadọta pere ninu oṣu keji yii gẹgẹ bii owo oṣu kọkanla, ọdun to kọja.

Eyi wa lara ohun to bi awọn dokita ijọba ninu ti wọn fi kede iyansẹlodi ọlọjọ gbọọrọ.

Nigba to n fun awọn dokita naa lesi ọrọ wọn, adele kọmisanna feto ilera nipinlẹ Ondo, Dokita Jibayọ Adeyẹye, ni o niye ọjọ to yẹ ki wọn fun ijọba ki wọn too bẹrẹ iru igbesẹ ti wọn gbe ọhun.

O ni ijọba ti n ṣeto ati ba awọn tinu n bi naa sọrọ kí wọn le pada sẹnu isẹ wọn lẹyẹ-o-ṣọka.

Leave a Reply