Nitori aabọ owo-osu to n san, ẹgbẹ oṣiṣẹ fẹẹ gbena woju Akeredolu l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ipinlẹ Ondo naa lawọn ti ṣetan ati gbena woju Gomina Rotimi Akeredolu lori aabọ owo-oṣu kọkanla, ọdun to kọja, to tun fẹẹ san fun wọn.

Ẹgbẹ ọhun ni awọn ti sọ ero ọkan awọn fun gomina lori ilana to fi gbọdọ san owo-osu awọn oṣiṣẹ ninu ipade tí awọn ṣe pẹlu awọn aṣoju ijọba lọjọ kejilelogun ati ikẹtalelogun, oṣu keji, ọdun yii.

Wọn ní aba tí awọn fi siwaju Arakunrin ni pe o gbọdọ san owo ajẹmọnu Covid-19 fawọn oṣiṣẹ eleto ilera, sisan ida aadọta owo-osu kọkanla, ọdun 2020, eyi to san ku tẹlẹ fun gbogbo oṣiṣẹ, ko si tun san ida ọgọrun-un owo oṣu kejila, ọdun kan naa, fun wọn.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ni ijọba ti gba lati san owo ajẹmọnu fawọn to n ṣiṣẹ lẹka eto ilera, ṣugbọn awọn ko ni i gba fun wọn ki wọn san ida aadọta tí wọn san ku fun oṣu kọkanla, ọdun to kọja, nikan gẹgẹ bii ohun ti wọn lawọn fẹẹ ṣe.

Apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ni gbogbo ọna lawọn fi ta ko ipinnu Gomina Akeredolu lori igbesẹ to fẹẹ gbe ọhun, wọn ni ọsẹ to n bọ yii lawọn fun un da ko fi san aabọ owo-osu kọkanla ati ẹkunrẹrẹ owo-osu kejila, ọdun to kọja, fawọn ọmọ ẹgbẹ awọn.

 

 

 

Leave a Reply