Nitori aabo to dẹnukọlẹ awọn oloye ilu n beere fun afikun agọ ọlọpaa ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni awọn oloye ọba labẹ Emirate, ke si ijọba ipinlẹ Kwara, labẹ isejọba Gomina Abdulrazak, pe ki wọn kọ agọ ọlọpaa kun eyi to wa nilẹ nipinlẹ naa ki eto aabo le gbopọn si i.
Awọn oloye ọhun labẹ isọkan Emirate ni wọn sọ ọrọ yii di mimọ lasiko ti wọn lọọ ṣe abẹwo si Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Tuesday Assayomo, ti wọn si sọ pe awọn nilo agọ ọlọpaa lawọn agbegbe bii Ejidongari, nijọba ibilẹ Moro, Oko- Olowo, nijọba ibilẹ Guusu Ilọrin, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Magaji Nda tiluu Ilorin, Alaaji Mohammed Salihu Woru, to lewaju awọn oloye ọhun sọ pe gbogbo igba ni awọn olugbe agbegbe Ejidongari, maa n tẹ ofin loju, ti ọpọ yoo si maa jaye fami-lete-ki-n-tutọ latari pe ko si agọ ọlọpaa ni agbegbe naa ti o si n ko ipaya ba awọn olugbe agbegbe ọhun. Bakan naa lo tẹsiwaju pe agbegbe Oko-Olowo, nijọba ibilẹ Guusu Ilọrin, nilo agọ ọlọpaa latari pe ṣe ni wọn n tẹ ofin loju ni agbegbe naa, ati pe ibẹ ni ẹnubode si Ariwa orile-ede yii, to si jẹ pe oniruuru awọn eniyan ni n de si agbegbe naa. Wọn fi kun un pe o ti to ọdun meji sẹyin ti wọn ti n beere fun iranwọ agọ ọlọpaa lawọn agbegbe ti iwa ọdaran si n peleke si lojoojumọ ṣugbọn ijọba ko ti i da wọn lohun.
Kọmisanna Tuesday Assayomo dupẹ lọwọ awọn oloye fun bi wọn ṣe mu eto aabo ni ọkunkundun to si ni ijọba yoo gbe igbesẹ lori awọn ibeere wọn.

Leave a Reply