Nitori aabo to mẹhẹ, awọn aṣofin Ogun ni ki gomina fofin de kanifa ati banga

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lati le gbegi dina wahala to maa n waye nibi ayẹyẹ opin ọdun ti wọn n pe ni kanifa, ati jiju banga to maa n ro gbamu bii ibọn, to si ṣee lo fawọn oniṣẹ ibi, ile-igbimọ aṣofin Ogun ti parọwa si Gomina Dapọ Abiọdun pe ko fofin de ayẹyẹ opin ọdun ti wọn maa n ṣe kiri adugbo, ko si tun fofin de banga yinyin pẹlu, nitori aabo ko fi bẹẹ si lasiko yii debi teeyan yoo tun maa ki ọwọ ara ẹ bọ ṣọọlọ.

Nibi ijokoo awọn aṣofin to waye lọfiisi wọn l’Oke-Mosan, lọsẹ to kọja, ni wọn ti fẹnuko si aba yii, iyẹn lẹyin ti olori ọmọ ẹgbẹ to pọ ju lọ, Ọnarebu Yussuf Sheriff, ti ṣide eto, ti Ọnarebu Sylvester Abiọdun to n ṣoju ẹkun Ariwa Ijẹbu naa si kin in lẹyin, ko too di pe gbogbo awọn aṣofin naa waa fọwọ si i.

Gẹgẹ bawọn aṣofin yii ṣe sọ, o ṣe pataki pe kijọba so ọdun kanifa naa kọ, nitori yoo koba eto aabo, o tun le jẹ ki Korona gbilẹ si i nibi ti wọn ba ti n ṣe ohun ti aisan naa ko fẹ.

Awọn aṣofin sọ pe gbogbo kanifa ti wọn ti ṣe sẹyin ko bimọ ire ri, afi jagidijagan to le da omi alaafia ilu ru, to si tun maa n mu ẹmi awọn ẹlomi-in lọ.

Nigba to n gba aba naa wọle, Abẹnugan ile ti i ṣe Ọnarebu Ọlakunle Oluọmọ, sọ pe fun anfaani ipinlẹ Ogun ati ijọba lawọn ṣe da aba yii.

O ni ile-igbimọ yii ko ni i faaye gba iwa janduku kankan labẹ kanifa ṣiṣe. Oluọmọ sọ pe ohun ti yoo di alaafia to wa nipinlẹ yii lọwọ ni kanifa ati banga yinyin, awọn ko si ni i faaye silẹ fun ayẹyẹ ti yoo tun mu Koro gbilẹ si i.

Lẹyin ti gbogbo ile-igbimọ fọwọ si aba yii tan, Oluọmọ taari ẹ si Akọwe ile, Ọgbẹni Deji Adeyẹmọ, pe ko taari aba naa si ọfiisi Gomina Dapọ Abiọdun, ati sọdọ awọn ẹṣọ alaabo gbogbo.

Leave a Reply