Nitori aala ilẹ, wọn lu Rasak pa l’Ọbafẹmi-Owode

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti mu awọn mẹta kan, Idowu Shorunkẹ, Daniel  Ikwe ati Micheal Tedungbe. Rasak Shotunde ni Daniel ati Micheal fọgi mọ lori lọjọ Keresimesi to kọja yii, Idowu lo si ran wọn pe ki wọn pa a nitori aala ilẹ to da oun ati oloogbe naa pọ.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣalaye pe awọn kan ni wọn ta ileeṣẹ ọlọpaa Owode-Ẹgba lolobo pe oku ọkunrin kan wa loju ọna to lọ si Abule Baṣẹyẹ, ori ọkunrin naa ti fọ nibi to ku si. O jọ pe wọn figi fọ ọ lori titi to fi ku ni. Abule kan ti wọn n pe ni Basomo ni wọn pa a si, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode.

Awọn ara agbegbe naa lo ran awọn ọlọpaa lọwọ ti ọwọ fi ba ọkan ninu awọn to pa oloogbe yii, ẹni tọwọ ba naa lo mu wọn lọ sọdọ ẹni keji ti wọn jọ paayan, awọn mejeeji si jẹwọ pe awọn lawọn lagi mọ oloogbe Rasak Shotunde lori to fi ku.

Wọn ni awọn dena de ọkunrin naa lasiko to n bọ lati Abẹokuta to ti lọọ wo ọmọ rẹ ọkunrin ni.

Abule wọn ni wọn lo n pada si lọjọ Keresimesi naa tawọn fi fọgi mọ ọn lori, to si ku.

Daniel ati Micheal fi kun alaye wọn pe Idowu lo ni bawọn ba le pa ọkunrin to n ba oun ja si aala ilẹ naa, oun yoo fun awọn ni idaji miliọnu naira. Wọn ni owo naa lawọn fẹẹ gba lọwọ ẹ tawọn fi pa a.

Nigba tọwọ ba Idowu ti wọn lo ran wọn niṣẹ ipaniyan yii, oun naa jẹwọ pe oun loun ran awọn meji yii lati pa oloogbe, nitori o pẹ to ti n ba oun ja si ilẹ kan, bo ba si ku, ohun to n run nilẹ aa tan, ohun to jẹ koun bẹ wọn lọwẹ iku si i niyẹn.

 Awọn ọlọpaa ti ko awọn mẹtẹẹta lọ si ẹka to n ri si ipaniyan, wọn si gbe oku oloogbe lọ si ile igbokuu-si.

Leave a Reply