Nitori afurasi ole to ku sọwọ ẹsọ Amọtẹkun, awọn ọdọ fẹhonu han l’Okitipupa

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Diẹ lo ku ki rogbodiyan bẹ silẹ lasiko tawọn ọdọ kan n fẹhonu han ta ko awọn ẹsọ Amọtẹkun niluu Okitipupa latari afurasi kan ti wọn lo ku mọ wọn lọwọ nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo lori ẹsun ole jija ti wọn fi kan an.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lawọn ẹsọ Amọtẹkun kan tawọn eeyan mọ si, Adon ati Oṣhọ fi pampẹ ofin gbe ọkunrin ti wọn n pe ni Papa, ẹni ti wọn fẹsun kan pe o ji foonu ọkan ninu wọn losu to kọja.

Ibi ti wọn si ti n gbiyanju ati fi tipatipa gba ọrọ silẹ lẹnu rẹ ni wọn lọkan ninu awọn ẹsọ Amọtẹkun naa ti gun un lọbẹ, leyii to pada ṣokunfa iku ọkunrin ẹya Ijaw ọhun.

Iṣẹlẹ yii lo ṣokunfa bawọn ọdọ kan ṣe jade lati fẹhonu han ta ko ọna ti wọn gba ran afurasi naa sọrun ọsangangan lai ti i mu un d’ele-ẹjọ.

Ọna marosẹ to gba ilu Okitipupa kọja lọ si Igbọkọda lawọn olufẹhonu han ọhun di pa, leyii to fa sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ ọkọ lagbegbe naa fun ọpọ wakati.

Ninu ọrọ ti ọkan ninu awọn ọdọ tinu n bi naa ba awọn oniroyin sọ, o ni awọn ko lodi rara si bi wọn ṣe fi panpẹ ofin gbe oloogbe ọhun, ṣugbọn ko yẹ ki wọn fiya jẹ ẹ titi to fi ku mọ wọn lọwọ nigba ti ko si kootu to ti i da ọkunrin naa lẹbi pe loootọ lo jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

O ni lara ohun ti awọn n beere fun ni pe kijọba ati ọga patapata fun ẹsọ Amọtẹkun gbiyanju ati maa ṣe idanilẹkọọ ati ilanilọyẹ fawọn oṣiṣẹ wọn loorekoore lati fopin siru iṣẹlẹ bẹẹ to le tun fẹẹ sẹlẹ lọjọ iwaju.

Leave a Reply