Nitori Agboọla to dara pọ mọ wọn, awọn ọmọ ẹgbẹ ZLP n binu kuro ninu ẹgbẹ l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ 

Ọgọọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party ni wọn ti binu kuro ninu ẹgbẹ ọhun lẹyin isẹju diẹ ti awọn asaaju ẹgbẹ kede ipinnu wọn lati faaye gba Igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Agboọla Ajayi, lati dije labẹ asia ẹgbẹ naa ninu eto idibo to n bọ yii.

Awọn ọmọ ẹgbẹ tinu n bi ọhun ni wọn ko ara wọn jọ si ile ijọba to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii, nibi ti wọn ti ṣeleri ati ṣiṣẹ pọ pẹlu Gomina Rotimi Akeredolu lasiko eto idibo naa.

ALAROYE gbọ pe aṣofin to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun Akoko ati Ariwa Iwọ-Oorun Akoko l’Abuja, Ọnarebu Olubunmi Tunji Ojo, lo saaju awọn tinu n bi naa wa sọdọ gomina.

Igbakeji alaga ZLP nipinlẹ Ondo, Abayọmi Adebayọ, to gba ẹnu awọn eeyan ọhun sọrọ ni igi lẹyin ọgba lawọn jẹ fun ẹgbẹ ZLP ti awọn ti n kuro.

O ni awọn iṣẹ takuntakun ti Gomina Akeredolu ti ṣe laarin ọdun diẹ to bẹrẹ iṣakoso lo ṣokunfa bi awọn ṣe pinnu ati ṣatilẹyin fun erongba rẹ lati dije lẹẹkeji.

Ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ ZLP to b’ALAROYE sọrọ ni ko si ọmọ ẹgbẹ awọn to lọọ darapọ mọ ẹgbẹ APC.

O ni lati inu oṣu keji, ọdun ta a wa yii, ni Abayọmi Adebayọ ati Fẹmi Ikoyi to jẹ akọwe ipolongo ti kuro ninu ẹgbẹ, ti wọn si lọọ da ẹgbẹ mi-in ti wọn pe ni Grassroot Progressive Network (GPN) silẹ.

O ni ọrọ oṣelu lasan ni ariwo ti wọn n pa pe ṣe lawọn ṣẹṣẹ n kuro ninu ẹgbẹ ZLP.

Ọjọ Aiku, Sannde yii, kan naa ni ALAROYE gbọ pe awọn asaaju ẹgbẹ ZLP lorilẹ-ede yii fimọ ṣọkan, ti wọn si fọwọ si Ọnarebu Agboọla Ajayi gẹgẹ bii oludije wọn ninu eto idibo gomina to n bọ.

Leave a Reply