Nitori agidi, ọkọ kọ Basira silẹ n’Ibadan, o loun ko ṣe mọ

Oloye Ademọla Ọdunade, ẹni ti ṣe Aarẹ kootu k’ọkọ-k’ọkọ to wa ni Mapo, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, ti tu igbeyawo ọdun mẹrinlelogun kan lori wahala buruku tawọn lọkọ-laya n ba ara wọn fa ka.

Ọlalekan Ṣoẹtan ati iyawo ẹ, Basirat, ni wọn jọ wọra wọn lọ siwaju adajọ ọhun, nibi ti ọkọ ti fẹsun kan iyawo ẹ pe alagidi ni. O ni ki i gbọnran, bẹẹ lawọn obi ẹ paapaa fara mọ gbogbo iwa ti obinrin naa hu si oun lọọdẹ, ati pe ẹnu oun ko ka a mọ rara.

Ọkunrin oniṣowo yii ti waa bẹ Aarẹ ile-ẹjọ naa ko tu awọn ka, ki kaluku maa ba tiẹ lọ.

Ni bayii, Oloye Ademọla Ọdunade ti ni ki awọn ọmọ meji to dagba ju ninu awọn ọmọ ti tọkọ-taya yii bi funra wọn maa ba baba wọn, Ṣoẹtan gbe, nigba ti eyi to kere ju laarin wọn gbọdọ maa gbe lọdọ Basirat, iyẹn iya wọn.

O ni ki alaafia le jọba laarin awọn mejeeji loun ṣe gbe idajọ ọhun kalẹ, ati pe ohun to foju han ni pe ko si ifẹ ati irẹpọ gidi mọ laarin wọn. Bakan naa lo ti paṣẹ fun ọkunrin yii lati maa fun iyawo ẹ ni ẹgbẹrun marun-un naira (N5000) gẹgẹ bii owo ounjẹ fun itọju ọmọ.

Ninu ọrọ Basira lo ti bẹ adajọ ko fun oun lanfaani lati ko awọn ọmọ oun sọdọ nitori igbeyawo ọhun ti su oun naa paapaa, ati pe ọkunrin kan ti ko nilaari rara, ti ki i ṣe ojuṣe ẹ deede ni Ọlalekan n ṣe.

Leave a Reply