Nitori ai tẹle ofin ile kikọ, ijọba Ogun ti ile mẹrindinlọgbọn pa ni Mowe

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ko din ni ile mẹrindinlọgbọn ati ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun, labẹ akoso ileeṣẹ to n ri si eto ilu ati ile kikọ, ti pa lọsẹ to kọja yii ni Mowe/Ọfada, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode. Wọn ni wọn lufin ile kikọ, wọn ko tẹle ilana to yẹ.

Yatọ si awọn ti wọn ti wọnyi, ẹka to n ri si eto ile kikọ naa tun kọwe le awọn mi-in lọwọ lati waa ṣalaye idi ti wọn fi kọle wọn, ileeṣẹ tabi ileepo sibi ti ko ba ilana ile kikọ mu.

Kọmiṣanaa fun eto ilu ati idagbasoke, TPL Tunji Ọdunlami, sọ eyi di mimọ lẹyin ayẹwo agbegbe yii ti wọn ṣe. O ni ijọba ti kilọ fawọn to n kọle ta ko ofin ijọba wọnyi pe ki wọn yee kọle, ileeṣẹ tabi ileepo sibi ti ko tọ, nitori eyi lewu, o si n ṣakoba fun idagbasoke ilu ni.

Nigba to n ṣalaye ọna tawọn ile ti wọn ti pa yii fi lodi sofin ile kikọ,  Ọdunlami sọ pe wọn ko faaye silẹ ni odiwọn ofin, ohun ti wọn kọ sori ilẹ yatọ si ohun to wa ninu iwe ikọle, kikọle mi-in yatọ si eyi ti wọn gbaṣẹ ẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ko too di pe awọn to n kọle kiri lai tẹle aṣẹ ile kikọ yii ba ipinlẹ Ogun jẹ, Kọmiṣanna ni ijọba ko ni i jẹ kiru ẹ waye, awọn yoo gbe igbesẹ to yẹ lori ẹni to ba kọle rẹ to fi tapa sofin ni.

Ọdunlami ṣalaye pe iwe aṣẹ ile kikọ sibi to yẹ ko nira lati gba nipinlẹ Ogun.  O ni tẹlẹ lo jẹ pe ọjọ mọkanlelaaadọta (51) ni yoo lo keeyan too le gba iwe aṣẹ ile kikọ nipinlẹ yii, nisinyii ti wọn ti tun ofin naa gbe yẹwo, ọjọ marun-un pere ni eeyan yoo fi gbawe yii to ba jẹ ileegbe lo fẹẹ kọ.

To ba jẹ okoowo lo fẹẹ fi ibi to fẹẹ kọ naa ṣe, ọjọ mẹrinla pere ni iwe rẹ yoo tẹ ẹ lọwọ lẹyin to ba ti lọọ forukọ silẹ lọdọ ijọba.

Nipa bi awọn ti wọn ti ile tabi ileeṣẹ wọn pa yii yoo ṣe yanju rẹ, wọn ni ki wọn lọ si ileeṣẹ to n ri ọrọ ile kikọ lati gbọ alaye lẹkun-un-rẹrẹ, ki wọn si mu awọn ẹri ti wọn ni lati kọle ti wọn ko gba aṣẹ rẹ naa wa.

Ijọba ti gbe igbimọ ti yoo ṣe amulo ofin tuntun lori ọrọ-epo bẹntiroolu kalẹ.

Leave a Reply