Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Iyawo Gomina ipinlẹ Ondo, Arabinrin Betty Akeredolu-Anyawu, ti fagi le ayẹyẹ nla kan to fẹẹ ṣe lati ṣami ayẹyẹ aadọrin ọdun to dele aye.
Ni kete ti aya gomina ọhun ti kede ìpinnu rẹ lati ṣayẹyẹ ọjọ ibi lọkan-o-jọkan awuyewuye ti n waye pẹlu bi awọn eeyan ṣe n bẹnu atẹ lu obinrin ọmọ bibi ipinlẹ Imo naa lori rẹ.
Ibeere tọpọ awọn eeyan si n beere lọwọ ara wọn, ṣugbọn ti wọn ko rẹni fun wọn lesi ni pe, ṣe o yẹ ki iyawo ile kan ronu ati ṣajọyọ ọjọ ibi, nigba ti ọkọ rẹ ṣi wa lẹṣẹ-kan-aye-ẹsẹ-kan-ọrun lọsibitu to ti ń gba ìtọ́jú? Wọn ní ọdaju obìnrin nikan lo le maa gbero iru nnkan bẹẹ lasiko yìí.
Bi awọn eeyan kan ṣe n fi aidunnu wọn han lori igbesẹ naa, ti wọn si n ta ko o, lawọn mi-in n fi atilẹyin wọn han si i, wọn ni ko sohun to buru ninu ohun to fẹẹ ṣe, niwọn igba to ti jẹ lara iṣẹ ilu ni.
Lara ohun tí obinrin àkọ́kọ́ naa fi sinu eto ayẹyẹ ọjọọbi rẹ ni rírìn ìrìn afẹ (fífi ẹsẹ rin) lati ilu Akurẹ, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ondo lọ siluu Ọwọ, ti i ṣe ilu ọkọ rẹ.
Iyanu lo jẹ fawọn eeyan ipinlẹ Ondo nigba ti Arabinrin deedee yi ipinnu rẹ pada lojiji laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹsan-an, oṣu Keje ta a wa yii, to si kede lori Fesibuuku rẹ pe oun ti fagi le ayẹyẹ nla naa.
Betty ni oun ti sun eto ayẹyẹ naa di ọjọ mi-in ọjọọre nitori idi kan tabi omi-in. Lẹyin eyi lo dupẹ lọwọ gbogbo awọn alatilẹyin rẹ fun aduroti wọn.