Nitori ajẹsilẹ owo-oṣu, awọn oṣiṣẹ fẹẹ gbena woju Akeredolu l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ 

Awọn aaaju ẹgbẹ oiẹ ipinlẹ Ondo ti fẹhonu wọn han si gomina ipinlẹ naa, Rotimi Akeredolu, lori ajẹsilẹ ọpọlọpọ owooṣu wọn.

Awọn adari ajọ oiẹ ọhun kilọ fun gomina ninu iwe kan ti wọn fi sọwọ si i lọjọ kẹwaa, osu keje, ọdun ta a wa yii, pe awọn fun un lọjọ marun-un pere ko fi san gbogbo ajẹsilẹ owoou to jẹ wọn.

Wọn ni ki gomina ọhun maa reti iyansẹlodi awọn ni gbogbo ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ Ondo to ba fi kọ lati dahun si ibeere awọn titi di Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ ọsẹ to n bọ yii.

Eyi lawọn ohun tawọn oisẹ n beere lọwọ ijọba ni ibamu pẹlu lẹta ti wọn kọ si gomina. Ajẹsilẹ owoosu kejila, ọdun 2016, fun awọn olukọ ile-ẹkọ alakọọbẹrẹ nìkan ati ajẹsilẹ owoou kin-in-ni, ọdun 2017, fun gbogbo oiẹ.

Awọn ẹtọ ti wọn tun n bẹbẹ fun ni, owo ajẹmọnu awọn oiẹ fun ọdun 2018 ati 2019, owo alajẹsẹku ti wọn n ba awọn olukọ ile-iwe girama yọ fun odidi ou marun-un gbako, owo ajẹmọnu awọn oiẹ eleto ilera to n mojuto didena ajakalẹ arun Korona, ida aadọta ajẹsilẹ owoosu awọn oifẹyinti atawọn nnkan mi-in.

Leave a Reply