Nitori Akeredolu, ojo wẹliwẹli pa Tinubu pẹlu Akande l’Ondo, wọn ni APC gbọdọ wọle ṣaa ni

Kazeem AderounmuNi ipinlẹ Ondo, loni-in ọjọ Abamẹta, Satide, wamuwamu bayii lẹsẹ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC pe, bi eto ipolongo idibo ẹgbẹ naa ti ṣe bẹrẹ ni pẹrẹu.

Gomina ipinlẹ ọhun, Arakunrin Rotimi Akeredolu, eni tawọn eeyan n pe ni Aketi lagbo oṣelu gan-an ni gbogbo wọn tori ẹ jade, ti wọn si n sọ funra wọn wi pe, aṣeyọri ni ẹgbẹ oṣelu APC gbọdọ fi idibo to n bo naa ṣe.

Lara awọn agbaagba ẹgbẹ ọhun ti wọn wa nibẹ ni Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, bẹẹ gẹgẹ ni ẹni to ti figba kan jẹ alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ ri, Alagba Bisi Akande, Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-olu, Gomina Abdulrahaman Abdulrasaq lati ipinlẹ Kwara, atawọn mi-in ti wọn jẹ eekan nla ninu ẹgbẹ oṣelu APC loju wọn pe, ti ẹsẹ si tun pele paapaa.

Ṣe ṣaaju asiko yii ni Aarẹ Muhammed Buhari ti sọ pe, ko si kinni kan bayii to le yẹ ẹ, Rotimi Akeredolu naa ni yoo tun jawe olubori ninu idibo gomina ti yoo waye lọjọ kẹwaa oṣu kẹwaa ọdun 2020 yii.

Tẹ o ba gbagbe, ninu idibo ọhun ni Gomina Rotimi Akeredolu yoo ti koju awọn eeyan wọnyi: Agboola Ajayi ti ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party ati Eyitayọ Jẹgẹdẹ, ẹni to n dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.

Bọla Tinubu ti ba awọn ọmọ Ondo sọrọ, ohun to si sọ ni pe, Akeredolu ti ṣe bẹbẹ o, iṣẹ to ṣe nipinlẹ naa laarin ọdun mẹta aabọ ki i ṣe ọrọ ẹjọ wẹwẹ, nitori awọn ohun manigbagbe ti kaluku le foju ri ni, ati pe ko maa ba iṣẹ ọhun lọ ni yoo ṣe gbogbo ọmọ Ondo lanfaani gidi.

Ninu ojo wẹliwẹli ni gbogbo wọn wa fun bii wakati mẹta, bi awọn oloṣelu lati ilẹ Yoruba nibi ṣe duro wamu, bẹẹ lawọn Hausa lọhun-un naa wa daadaa, ti kaluku si sọ idi pataki ti Akeredolu fi gbọdọ tun pada sipo ọhun lẹẹkan si i.

Ṣa o, o jọ pe, awọn APC n mura gidigidi o, nibi ti awọn ọmọ Ondo fẹẹ lọ gan-an lori ọrọ ibo gomina to delẹ yii, ko ni pẹ ti gbogbo aye yoo ri i.

 

Leave a Reply