Nitori akọlu awọn janduku, INEC sun awọn eto idibo kan siwaju l’Ekoo

Faith Adebọla

Pẹlu bi eto idibo sipo gomina ati ileegbimọ aṣofin ipinlẹ ṣe waye nipinlẹ Eko lọjọ Abamẹta Satide, ọjọ kejidinlogun oṣu Kẹta yii, gẹgẹ bii tawọn ipinlẹ yooku ni Naijiria, ajọ INEC ti kede pe eto idibo ko waye lawọn ibudo idibo bii mẹwaa kan nipinlẹ naa, nitori ewu akọlu awọn janduku, latari eyi, wọn ti sun eto idibo apa ibẹ siwaju di ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta yii.

Awọn ibubo idibo tọrọ naa kan wa ni agbegbe Victoria Garden City, VGC, eyi to wa lagbegbe Lẹkki, l’Erekuṣu Eko.

Kọmiṣanna fun ajọ eleto idibo apapọ, Independent National Electoral Commission, nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Oluṣẹgun Agbaje, to kede ayipada yii lọsan-an ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta yii, sọ pe awọn oṣiṣẹ eleto idibo atawọn agunbanirọ tawọn yan lati lọọ ṣiṣẹ ni VGC ta ku pawọn o lọ, wọn ni ohun toju awọn ri lasiko eto idibo sipo aarẹ ati ileegbimọ aṣofin apapọ, eyi to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, ko bara de, wọn ni niṣe ni wọn mu awọn lẹru nibẹ, tawọn janduku ko jẹ kawọn le ṣiṣẹ awọn bo ṣe yẹ, ti apa awọn agbofinro ko si ka wọn. Eyi lo mu ki ọpọ wọn taku pawọn o lọ sibẹ lọtẹ yii.

Agbaje ni awọn tun ṣapa lati ko awọn nnkan eelo idibo lọ sẹnu geeti ati wọ VGC yii, sibẹ ibẹru akọlu awọn ọmọ isọta ko jẹ kawọn araalu fẹẹ jade waa dibo nibẹ.

O leyii lo mu kawọn sun eto idibo apa ibẹ siwaju si ọjọ Aiku, Sannde, eyi ti yoo mu ki awọn agbofinro to pọ wa larọọwọto, ti ọkan awọn oṣiṣẹ awọn yoo si balẹ, kawọn eeyan ibẹ le lanfaani lati ṣe ojuṣe wọn gẹgẹ bii ọmọ Naijiria rere.

Agbaje ni: “Ibudo idibo mẹjọ lo wa nibi, awọn oludibo ti iye wọn jẹ ẹgbẹrun mẹfa ati mẹrinlelogun lorukọ wọn wa lakọọlẹ lati dibo, awọn ẹgbẹrun marun-un, okoolelẹgbẹta ati mẹrin (5,624) ni kaadi idibo alalopẹ wọn ti wa lọwọ wọn, bẹẹ la si tun ni ibudo idibo meji lọhun-un yẹn, nibi ẹnu ọna abawọle sibi.

Lẹyin ta a ti fori kori lori ọrọ yii, pẹlu aṣẹ lati olu-ileeṣẹ ajọ INEC, a ti pinnu lati ṣeto idibo ti agbegbe yii lọla, a maa ko ẹru wa sibi laago mẹjọ aabọ aarọ, eto idibo yoo si waye”, gẹgẹ bo ṣe wi.

Lara awọn ibudo idibo tọrọ naa kan ni PU 032, PU 033, PU 119 si 124 atawọn mi-in.

Leave a Reply