Nitori akọlu awọn janduku to waye, ijọba wọgi le irinajo reluwee Abuja si Kaduna

Faith Adebọla

 Latari akọlu tawọn janduku agbebọn ṣe si ọkọ reluwee to n lọ lati Abuja si ilu Kaduna, ti wọn si ba reluwee naa jẹ, ti wọn si ba awọn oju-irin to n tọ jẹ pẹlu, ileeṣẹ reluwee ilẹ wa, Nigerian Railway Corporation (NRC) ti so irinajo reluwee loju ọna naa rọ na, wọn si ti wọgi le itolẹsẹẹsẹ irinajo reluwee ibẹ.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ naa fi lede lori ikanni ayelujara wọn, Ọga agba NRC, Ọgbẹni Fidet Okhiria, fidi ẹ mulẹ pe loootọ lawọn agbebọn ṣakọlu si reluwee ọhun, wọn ba iwaju ati awọn ibi kan nibi agbari reluwee naa jẹ, wọn si fi bọmbu ba awọn oju irin jẹ.
O ni iṣẹlẹ yii waye lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Bakan naa ni Ọgbẹni Paschal Nnorli to jẹ maneja ibudokọ reluwee Abuja si Kaduna fidi ẹ mulẹ pe nnkan kan to dun bii bọmbu lo ṣokunfa akọlu naa.

O sọ fakọroyin iweeroyin Punch pe “bẹẹ ni o, wọn ṣakọlu si wa, a o ti i mọ pato nnkan to fa a, ṣugbọn iwadii ti bẹrẹ. Lasiko yii, a ti wọgi le gbogbo igbokegbodo wa lagbegbe yii.

Ọgbẹni Lanre Ayọọla to loun wa ninu reluwee yii nigba tiṣẹlẹ naa waye sọ lori ikanni fesibuuku rẹ pe agbegbe Dutse si teṣan Rijana, niṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ. O loun dupẹ pe Ọlọrun ko awọn yọ, tori niṣe lawọn janduku naa kọkọ ri awọn nnkan abugbamu mọ ọna oju irin ti ọkọ naa n tọ bọ, ẹyin eyi ni wọn bẹrẹ si i rọjo ibọn si ọkọ naa. O ni iṣẹ iyanu ni bawọn ṣe mori bọ.

Leave a Reply