Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ.
Apapọ awọn ẹgbẹ oṣelu lorilẹ-ede yii (CNPP), ti rawọ ẹbẹ si Aarẹ Muhammadu Buhari lati tete wa nnkan ṣe lori ọrọ akọlu to n waye lati ọwọ awọn ẹgbẹ APC ipinlẹ Ondo latari eto idibo to n bọ lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun ta a wa yii.
Alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Rotimi Bọboye, to gba ẹnu wọn sọrọ ninu ipade awọn oniroyin kan to waye l’Akurẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, sọ pe gbogbo rogbodiyan oṣelu to n waye kaakiri ipinlẹ naa ko sẹyin ẹgbẹ APC.
O ni kekere ni rogbodiyan to waye lasiko eto idibo ijọba ibilẹ to kọja yoo jẹ lara eyi to ṣee ṣe ko ṣẹlẹ lasiko eto ibo gomina.
Ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ ADC niluu Ondo ati SDP Idanre ti wọn ṣe leṣe lo ni wọn ṣi wa lẹsẹ-kan-aye, ẹsẹ-kan-ọrun nile-iwosan ti wọn ti n gba itọju.
Lẹyin eto idibo yii lo ni Isaac Kekemeke to jẹ alaga ana fẹgbẹ APC nipinlẹ Ondo tun ko awọn eeyan kan jọ, to si n sọ fun wọn nipa erongba wọn lati da wahala silẹ lọjọ idibo.
O fi kun un pe ọsẹ to kọja yii lawọn tọọgi APC tun lọọ ṣe akọlu mi-in sawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ZLP nibi ti wọn ti n ṣepade lọwọ l’Akungba-Akoko.
Ohun to ni o ya awọn lẹnu ju ni bo ṣe jẹ pe awọn to lọọ fẹjọ sun ni tesan gan-an lawọn ọlọpaa tun mu, ti wọn si ti wọn mọle, ti wọn fi awọn to yẹ ki wọn mu silẹ ti wọn n rin kiri bo ṣe wu wọn.
Ọgbẹni Bọboye ni awọn asaaju ẹgbẹ oṣelu bii ogoji ni awọn pinnu lati ko ara wọn jọ lọjọ naa lati bẹ Aarẹ Buhari ko tete ba ẹgbẹ APC sọrọ nibi ti wọn ti n gbọ kọrọ yii too di ogun ati wahala tapa ko ni i ka mọ bii tọdun 1983.
Alaga ẹgbẹ ZLP nipinlẹ Ondo, Joseph Akinlaja, ni bo tilẹ jẹ pe awọn ko ba wọn kopa ninu eto idibo ijọba ibilẹ to kọja, sibẹ ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ awọn lawọn tọọgi fọwọ ba, ti wọn si ṣe wọn leṣe yanna yanna.