Nitori awọn ibeji Akeugbagold ti wọn ji gbe lọjọsi, ile-ẹjọ sọ awọn meje satimọle

Ọlawale Ajao, Ibadan

Awọn mejeeje ti wọn fẹsun kan pe wọn lọwọ ninu bi wọn ṣe ji awọn ibeji Sheik Taofeeq Akeugbagold, gbe n’Ibadan ti dero ahamọ.

Lọjọ Aje, Mọnde, l’Onidaajọ Emmanuel Idowu ti ile-ẹjọ Majisireeti to wa ni Iyaganku, n’Ibadan, paṣẹ ọhun nigba ti ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, gbe wọn lọ si kootu fun ẹsun ijinigbe.

Orukọ awọn olujẹjọ ti wọn fẹsun kan ọhun ni: Mohammed Bashir,  ẹni ọdun mẹtalelọgbọn (33); Oyelẹyẹ Ọpẹyẹmi, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25); Olumide Ajala, ẹni ọdun mẹrindinlogoji (36); Taiwo Ridwan, ẹni ọgbọn (30) ọdun;  Rafiu Mutiu, ẹni ọdun marundinlogoji (35); Fatai Akanji,  ẹni ọdun mọkandinlaaadọta (49) ati obinrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29) kan to n jẹ Modinat Rafiu.

Ẹsun marun-un ọtọọtọ to ni i ṣe pẹlu ijinigbe ati igbimọ-pọ huwa ọdaran ni wọn fi kan wọn nile-ẹjọ.

Agbèfọ́ba, Sajẹnti Oluṣẹgun Adegboye, to ṣoju ọga agba ọlọpaa ni kootu  ṣalaye lasiko ijẹjọ ọhun pe Mohammed, Oyelẹyẹ, Ajala, Taiwo, Rafiu ati Fatai ni wọn wọnu ile Akeugbagold to wa l’Ọjọọ, lọna Ṣaṣa, n’Ibadan, lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun 2020 yii, ti wọn si ji awọn ibeji naa ti wọn jẹ ọmọ ọdun meji ati oṣu mẹrin gbe lọ.

O ni lẹyin naa ni wọn gba miliọnu mẹrin Naira lọwọ agba oniwaasi naa ki wọn too yọnda awọn ọmọ ẹ fun un lẹyin ọsẹ kan ti wọn ti ji wọn gbe.

Lẹyin ti wọn ka awọn ẹsun ọhun si wọn leti, adajọ ko fun wọn lanfaani awijare kankan to fi paṣẹ pe ki wọn ti awọn maraarun mọnu ahamọ awọn ọlọpaa to n gbogun ti idigunjale ti wọn n pe ni SARS, n’Ibadan.

Lẹyin naa l’Onidaajọ Idowu paṣẹ pe ki wọn gbe akọsilẹ ẹjọ naa lọ si ileeṣẹ ọrọ ofin ati eto idajọ ni ipinlẹ Ọyọ fun itọsọna, eyi ti yoo jẹ ki ile-ẹjọ Majisireeti naa mọ boya awọn olujẹjọ lẹjọ ọ jẹ tabi bẹẹ kọ.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keje, oṣu kẹwaa, ọdun 2020 yii, ni wọn sun igbẹjọ naa si bayii.

 

Leave a Reply