Nitori awọn ṣọja apaayan, ijọba Amẹrika binu si Buhari

Ijọba Amẹrika binu si Buhari, wọn ni ko wa awọn ṣọja to paayan ni Leki jade

Inu ijọba orilẹ-ede Amẹrika ko dun rara si ohun to ṣẹlẹ nilẹ wa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja yii, nibi ti awọn ṣọja kan ti yinbọn lu awọn ọdọ ti wọn n ṣewọde jẹjẹ wọn. Nidii eyi, akọwe ijọba ibẹ, Ọgbẹni Michael Pompeo, ti ni ki Ọgagun Muhammed Buari ti i ṣe olori ijọba Naijiria wa awọn ṣọja apaayan naa sita o, ki wọn si fiya jẹ gbogbo awọn ti wọn wa nidii ọrọ naa.

Bi ọrọ ko ba le tan pata, ijọba Amẹrika ki i da si ọrọ orilẹ-ede mi-in, ti wọn yoo ba si da si i, ambasadọ, iyẹn aṣoju iru orilẹ-ede bẹẹ, ni yoo sọ ohun to ba wa lọkan ijọba wọn. Ṣugbọn ọrọ to ba ti di pe akọwe ijọba Amẹrika funra ẹ lo kọwe jade lori ẹ, ọrọ naa ti di ti gbogbo aye. Nibi yii ni ọrọ naa ti di ibẹru fawọn ti wọn  n ṣejọba wa paapaa.

Akọwe Amẹrika yii ni ohun to lodi si ofin ẹtọ ọmọniyan lagbaaye ni ki awọn kan ko ara wọn jọ lati ṣewọde, ki ijọba ibẹ si dẹ awọn ṣọja si wọn lati fi agbara mu wọn ati lati pa wọn. “Iwa naa ki i ṣe eyi to dara o, bẹẹ ni ko ba ilana ijọba dẹmokiresi ti gbogbo aye n ṣe mu!” Bẹẹ ni Michael Pompeo, akọwe ijọba Amẹrika, sọ sinu iwe to fi ranṣe sita lorukọ ijọba wọn.

Okunirn naa ni inu ijọba Amẹrika dun nigba ti wọn gbọ pe ijọba Naijiria ni awọn yoo gbe iwadii dide lori ohun to ṣẹlẹ yii, pe iwadii naa lawọn n reti, ki awọn too le da si ọro naa daadaa. O tiẹ binu si awọn ṣọja, o ni iṣẹ ti ko kan wọn ni wọn n ṣe, nitori ko si ohun to kan wọn rara lati da si ọro iwọde.

Leave a Reply