Nitori awọn adigunjale to wọle, ọlọpaa ti mu awọn oṣiṣẹ kan nile MKO Abiọla

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, ti kede pe iwadii nla n lọ lori ọrọ awọn adigunjale kan ti wọn wọ ile oloogbe Moshood Kaṣimawo Abiọla loru mọju ana, ti wọn si ko awọn nnka olowo iyebiye lọ. Ọga ọlọpaa yii pata funra rẹ lo lọ sile awọn Abiọla lati foju ara rẹ ri ohun to ṣẹle nibẹ gan-an.

Nibẹ ni wọn ti ṣalaye fun un pe ọna inu irà kànáà kan to wa lẹyin ile awọn Abiọla lawọn adigunjale naa ba wọle, nitori niṣe ni wọn da ogiri fẹnsi lu, ti wọn si faya fa bii ejo wọ inu ile wọn. Nigba ti awọn kan wọ inu ile, awọn mi-in duro sita lati maa ṣọna fun wọn. Awọn mẹta ni wọn wọle, ẹni kan naa lo si mu ibọn dani ninu wọn.

Odumosu ni, bi iku ile ko pani, tode ko le paayan, o ṣee ṣe ki ọrọ naa ni ọwọ awọn araale ninu. Boya ni ko jẹ eyi ni wọn fi ko awọn bii mẹta kan ninu awọn ọṣiṣẹ ile Abiọla yii, ti wọn ni wọn fura si wọn pe irin wọn ko mọ, wọn yoo tori ẹ fọrọ wa wọn lẹnu wo, ki wọn le mọ bi wọn mọ nipa iṣẹlẹ naa tabi wọn ko mọ.

Tundun, Ọkan ninu awọn ọmọ Abiọla, sọ pe nigba tawọn ole naa de, gbogbo ile ni wọn bẹre si i tu, ti wọn n wa oriṣiriṣi nnkan ti wọn le ji lọ. Nigbẹyin, awọn ole naa ko awọn ohun-ini bii goollu olowo nla ati ọpọlọpọ owo rẹpẹtẹ lọ, bo tilẹ jẹ pe wọn ko ṣe ẹnikẹni leṣe.

Leave a Reply