Nitori awọn agbẹ ti wọn ji gbe, awọn agbofinro ya wọnu igbo agbegbe Oke-Ogun

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Nitori bi awọn ajinigbe ṣe ji awọn agbẹ mẹrin gbe lagbegbe naa, awọn agbofinro ti lu agbegbe Oke-Ogun pa.

Kọmiṣanna feto iroyin ati irinajo afẹ ni ipinlẹ Ọyọ, Ọmọwe Wasiu Ọlatubọsun, lo fidi iroyin yii mulẹ nirọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

Nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 yii, lawọn igiripa ọkunrin kan ti wọn dihamọra pẹlu ibọn, ya wọ inu oko nla kan ti awọn agbẹ pọ si, ti wọn si ji mẹrin ninu wọn gbe.

Awọn ti ori ko yọ ninu awọn agbẹ yii ni wọn dele royin pe bii mẹwaa lawọn ẹruuku to waa ka awọn mọ inu oko ati pe aṣọ ṣọja ni wọn wọ, ti wọn si dihamọra pẹlu ibọn bii ẹni to n lọ soju ogun.

Wọn ni awọn ti wọn gbe lọ wọnyi jẹ diẹ ninu awọn to n mojuto awọn ẹlẹdẹ ti wọn n sin ninu ọgba oko nla to wa fun oniruuru ohun ọgbin pẹlu awọn nnkan ọsin naa.

Gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ awọn agbẹ aladaa nla to dako si agbegbe naa, Ọgbẹni Adepọju, ṣe sọ, ọna Okeho, nijọba ibilẹ Itẹsiwaju, lawọn agbebọn yẹn gbe awọn eeyan wa ti wọn ji gbe lọ, awọn ọlọpaa atawọn Amọtẹkun ti wọnu igbo yẹn ti wọn

“Ijọba lo n pariwo pe ka maa dako, oko ọhun naa la n da ta a fi di ẹni ti awọn ajinigbe n ji gbe yii lai ṣe adiẹ”.

Gẹgẹ bo ṣe wa ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn oniroyin lori ẹrọ ayelujara, Ọmọwe Ọlatubọsun fidi ẹ mulẹ pe awọn agbofinro bii ọlọpaa, Opereation Burst, Amọtẹkun, ati bẹẹ bẹẹ lọ ti gbakoso inu igbo ilu Isẹyin si Ipapo, lọ sọna Ṣaki bayii, ati pe laipẹ rara lawọn ṣọja naa yoo darapọ mọ wọn ninu igbiyanju lati gba awọn agbẹ ti wọn ji gbe naa silẹ laaye.

Leave a Reply