Nitori awọn ajinigbe ati adigunjale, awọn agbaagba Yoruba fẹẹ ṣepade nla n’Ibadan

Nitori bi awọn ajinigbe ṣe n pitu lọtun-un, ti awọn adigunjale n ṣoro losi lojoojumọ,
ajọ Iṣọkan ati Aabo Yoruba l’Agbaaye fẹẹ ṣepade nla n’Ibadan.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2022 yii, lapero ọhun yoo waye nileetura Kankanfo Inn, to wa laduugbo Ring Road, n’Ibadan.
Nnu apero ọhun lawọn agbaagba ilẹ Yoruba ti ọrọ iṣọkan ati eto aabo jẹ logun yoo ti jiroro lori idasilẹ ikọ alaabo alagbara kan ti yoo maa daabo bo ilẹ Oodua lọwọ ogun awọn agbesunmọmi ti wọn n jiiyan gbe, digunjale, ti wọn si n ṣeku paayan kaakiri lojoojumọ.
Nigba to n kede eto ọhun ninu ipade oniroyin agbaye to waye n’Ibadan, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ti i ṣe ọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla, ọdun yii, Ọgbẹni Victor Taiwo, ẹni to gbe ajọ Iṣọkan ati Aabo Yoruba l’Agbaaye kalẹ, sọ pe ninu ipade ọhun ni wọn yoo ti kede igbimọ majẹẹ-o-bajẹ kan ti yoo maa mojuto ipinnu ajọ naa lori iṣọkan ati eto aabo ilẹ Yoruba.
 
Ọgbẹni Taiwo, ẹni to bu ẹnu atẹ lu eto agbekalẹ ileeṣẹ ọlọpaa orileede yii, fara mọ ki ipinlẹ kọọkan maa mojuto awọn agbofinro tiwọn.
 
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Awọn ọmọ Yoruba ti orukọ wọn ko labawọn lawujọ la maa kede gẹgẹ bii igbimọ majẹẹ-o-bajẹ. Igbimọ yii ni yoo ṣagbekalẹ eto ta a ti ni nilẹ lati jẹ ki ohun gbogbo maa ri bo se yẹ ko ri nipa eto aabo nilẹ baba wa.
‘Nigba ti ẹni to fẹẹ ṣe wa nijanba ba gbe ibọn lọwọ, awa o waa le mu kumọ tabi igbalẹ lọwọ pade ẹ, ka la a fẹẹ daabo bo ara wa, iku loluwarẹ fi n ṣere yẹn.
“Ijọba ti ṣe diẹ nipa idasilẹ Amọtẹkun, ṣugbọn owo ti ijọba ya sọtọ fun eto aabo ko ran nnkan kan. Ohun ti ijọba ni lati ṣe ni lati fọwọsowọpọ pẹlu wa lori eto ta a gbe kalẹ yii, ki wọn ṣamulo awọn agbofinro ibilẹ wa to wa gẹgẹ bii ọmoogun tiwa.
“Ti ijọba ba fẹẹ gba ẹgbẹrun lọna ogun (20,000) akọni eeyan sinu iṣẹ eto aabo, o wa ni ikawọ wa nibi, awọn lẹgbẹlẹgbẹ to lọmọ ogun lọwọ loriṣiiriṣii nilẹ Yoruba la maa pe, wọn aa fun wa.
“Taa ba ti ni ifẹ ati iṣọkan, ko si nnkan ta a fẹẹ ṣe ti apa wa ko ni i ka. Ti gbogbo wa ba fẹnu ko pe a ni lati gba ara wa silẹ lọwọ awọn ọdaran, nnkan to ṣe e ṣe daadaa ni”.
 Ninu ọrọ tiẹ, ọkan ninu awọn alamoojuto ẹgbẹ Iṣọkan ati Aabo Yoruba, Ọjọgbọn Adegbọlagun George, rọ ijọba ati gbogbo ọmọ Yoruba lati tẹwọ gba eto ipinnu ẹgbẹ yii fun anfaani ilẹ.

Leave a Reply