Nitori awọn akẹkọọ ti wọn ji ko ni Katsina, gomina ti ileewe pa

Pẹlu bi awọn janduku ajinigbe kan ṣe kọ lu ileewe girama kan nipinlẹ Katsina, Gomina Aminu Bello Masari, ti kede pe ki wọn ti gbogbo ileewe tawọn akẹkọọ n gbe ibẹ, ki kaluku si gba ile wọn lọ.

Furaidee, ọjọ Ẹti, to kọja, lawọn janduku ajinigbe kan kọ lu ileewe, Government Science Secondary School, nibi ti wọn ti ji ọpọ awọn ọmọleewe ti ẹnikẹni ko ti i le sọ iye wọn gbe, nijọba ibilẹ Kankara, nipinlẹ Katsina.

ALAROYE gbọ pe awọn akẹkọọ ti wọn ti le diẹ ni irinwo (40̂6) ni wọn ti ri gba pada bayii gẹgẹ bi Kọmiṣanna fun eto ẹkọ nipinle naa, Ọjọgbọn Badamasi Chanchi, ṣe sọ.

Lasiko to n ba awọn ọmọleewe atawọn obi sọrọ nileewe ti wọn kọ lu yii lo fidi ọrọ ọhun mọlẹ. O ni pupọ ninu awọn ọmọleewe to raaye sa mọ awọn janduku ọhun lọwọ ni wọn sun inu igbo mọju, ki wọn too pada sileewe wọn.

Bakan naa lo sọ pe awọn ọmọ ti awọn obi wọn ti yọju bayii lawọn ti fa le awọn obi wọn lọwọ, ati pe gbogbo ileewe tawọn ọmọ n gbe inu  ọgba pata nipinlẹ Katsina ni awọn yoo ti pa bayii gẹgẹ bii aṣẹ gomina.

Saaju ikede yii, ni kete ti wọn ti ji awọn ọmọ ọhun gbe nileeṣẹ ọlọpaa naa ti bẹ jade lati ṣawari wọn, ninu eyi ti wọn ti ri awọn ọmọleewe bii igba, ti awọn mi-in ti wọn le diẹ ni igba (206) si fẹsẹ ara wọn rin pada, lẹyin ti wọn ti bọ lọwọ awọn to ji wọn gbe.

Ni bayii, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa, SP Gambo Isah, ti sọ pe awọn ẹṣọ ologun ori ilẹ ati toju ofurufu naa ti bẹrẹ iṣẹ bayii lati ṣawari awọn yooku ti wọn ji ko ọhun.

Agbẹnusọ yii sọ pe ̀ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja niṣẹlẹ ọhun waye, ni deede aago mẹwaa aṣaalẹ ku ogun iṣẹju. O ni bi awọn janduku ọhun ṣe kọ lu ileewe naa lawọn ọlọpaa paapaa ti dide ogun si wọn, eyi to mu diẹ ninu awọn ọmọleewe ọhun raaye sa mọ wọn lọwọ.

Ọlọpaa kan la gbọ pe o fara pa ninu iṣẹlẹ naa, to si ti n gba itọju bayii.

Bẹ o ba gbagbe, ko ti i pe wakati mẹrinlelogun ti Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari to jẹ ọmọ ipinlẹ naa de si ipinlẹ ọhun, nibi ti wọn ni o ti feẹ waa fara nisinmi.

Leave a Reply