Nitori awọn Fulani, Akeredolu ni ki wọn gba awọn oṣiṣẹ tuntun sinu ẹsọ Amotẹkun

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Gomina Rotimi Akeredolu ti fọwọ si gbigba ọgọọrọ awọn oṣiṣẹ sinu ẹsọ Amotẹkun, ẹka tipinlẹ Ondo.

Akọwe ẹsọ aabo ọhun, Ọgbẹni Lanre Amuda, lo ṣe ikede naa ninu atẹjade to fi sita lorukọ ọga wọn, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.

O ni Arakunrin Akeredolu ti fọwọ si eto igbanisisẹ naa latari ipenija lori eto aabo tawọn eeyan ipinlẹ Ondo koju lọwọ.

O ni igba kejì ree tijọba n ṣeto gbigba awọn eeyan ṣiṣẹ Amọtẹkun laarin ọdun kan pere.

Awọn ti wọn fẹẹ gba gẹgẹ bii oṣiṣẹ Amọtẹkun ni saa yii pín si isọri mẹta ọtọọtọ.Isọri akọkọ ni awọn ti yoo jẹ ojulowo oṣiṣẹ, ekeji ni awọn ọtẹlẹmuyẹ, nigba ti ipele kẹta yoo jẹ awọn to fẹẹ finu findọ ṣiṣẹ sin ijọba, o ni aaye igbanisisẹ yii si silẹ fun awọn tọjọ ori wọn wa laarin ogun si aadọrin ọdun nikan.

 

Bakan naa lo ni ara awọn olukopa wọnyi gbọdọ ji pepe, ki wọn jẹ ọmọluabi ati ẹni to mọ agbegbe rẹ daadaa.

Leave a Reply