Nitori awọn gomina to n ṣẹwọn to tu silẹ, Fẹmi Falana sọko ọrọ si Buhari

Faith Adebọla
Ilumọ-ọn-ka ajafẹtọọ ọmọniyan ati amofin agba nilẹ wa nni, Oloye Fẹmi Falana, ti sọko ọrọ si Aarẹ Muhammadu Buhari ati iṣakoso rẹ, latari ipinnu ti wọn ṣe lati fori jin gomina tẹlẹ, Jolly Nyame, to n ṣẹwọn lọwọ fun ẹsun ṣiṣe owo ilu mọkumọku ati jibiti.
Falana ni o ya oun lẹnu pe ijọba Buhari to n pariwo pe awọn n gbogun tiwa ibajẹ ati ajẹbanu le ṣe iru ipinnu buruku bẹẹ, o ni labẹ ofin ilẹ wa, aparo kan ko ga ju ẹgbẹ rẹ lọ, ohun ti gomina ọhun ba fi lanfaani si aforiji ijọba, afi ki wọn yaa fori ji awọn ẹlẹwọn yooku to jẹ ole jija lo sọ wọn dero ẹwọn bii tiwọn.
Nibi ayẹyẹ iranti ajafẹtọọ ọmọniyan ati Alukoro apapọ ẹgbẹ Afẹnifẹre tẹlẹ, Oloogbe Yinka Odumakin, eyi to waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹrin yii, ni gbọngan apero ileetura Sheraton, to wa n’Ikẹja, nipinlẹ Eko, ni Falana ti sọrọ ọhun.
Ṣe, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹrin to ṣaaju ni ipade awọn oluṣejọba ana ati toni waye niluu Abuja, eyi ti Aarẹ Buhari ṣalaga wọn. Nibi ipade naa ni wọn ti fẹnu ko lati dari ẹṣẹ ji gomina tẹlẹ fun ipinlẹ Taraba, Rẹfurẹndi Jolly Nyame, ki wọn si da a silẹ lalaafia.
Ninu oṣu Karun-un, ọdun 2018, ni Adajọ Adebukọla Banjoko tile-ẹjọ giga apapọ kan l’Abuja, sọ ọkunrin naa sẹwọn ọdun mejila, wọn lo jẹbi ẹsun ole jija ati ikowojẹ, ile-ẹjọ giga ju lọ nilẹ wa si fontẹ lu idajọ naa lọdun 2020. Latigba naa ni Nyame ti n fẹwọn jura lọgba ẹwọn Kuje, l’Abuja.
Ninu ọrọ rẹ gẹgẹ bii olubanisọrọ pataki nibi ayẹyẹ iranti oloogbe ọhun, Oloye Falani ni:
“Naijiria ti di ẹni amuṣẹfẹ lawujọ awọn orileede nla nla lagbaaye, tori ẹ lo fi jẹ pe ẹni yoowu ti wọn ba fẹẹ fa ọkọ iṣakoso orileede yii le lọwọ, ọkọ to ti dẹnu kọlẹ ni wọn fẹẹ gbe fonitọhun, ko le kuro loju kan.
“Ti wọn ba n sọ pe ijọba maa tẹsiwaju, iṣejọba ajalu, aisi ẹtọ, aisi idajọ ododo ati iwa ibajẹ ajẹbanu ni wọn fẹẹ mu tẹsiwaju.
“Ṣe ẹ ri i bi wọn ṣe n dariji ara wọn nisinyii, ẹni to ni niṣe loun waa gbogun ti iwa ajẹbanu naa lo tun n ṣaforiji fawọn ti wọn jale yii, wọn ṣaforiji fun ẹni to ko ọpọ biliọnu Naira owo ilu jẹ.
“Ero temi lori ẹ ni pe ki wọn yaa sọ fun Buhari, ko tu gbogbo awọn ti wọn n ṣewọn ole jija lọwọ silẹ, tori aparo kan ko ga ju ọkan lọ labẹ ofin ilẹ wa.
“Ni abala kẹtadindinlogun iwe ofin wa, o ni gbogbo ọmọ orileede yii gbọdọ ni ẹtọ kan naa, isọri kejilelogoji si sọ pe ko gbọdọ si ojuṣaaju lori ipo, ẹya, ede tabi nnkan mi-in ninu ajọṣe awọn ọmọ Naijiria.
“Ti Buhari ko ba tu wọn silẹ, mo gba awọn lọọya nimọran pe ki wọn kọri sile-ẹjọ lori ọrọ yii, ki wọn rọ ile-ẹjọ lati tu awọn onibaara wọn to n ṣẹwọn lori ẹsun ole jija silẹ, tori ibi ko ju ibi, ba a ṣe b’ẹru la b’ọmọ, ko si si bi ọbọ ṣe ṣori t’inaki o ṣe.
“Ti Buhari ba fẹẹ foriji ọrẹ ẹ to n ṣẹwọn, afi ko yaa foriji awọn yooku naa, ẹṣẹ ole ni wọn da, ole si lole i jẹ.”

Leave a Reply