Nitori awọn janduku ọmọ ẹgbẹ okunkun, ijọba ti ileewe pa l’Ọṣun

Ijọba ipinlẹ Ọṣun, ti ni ki wọn ti ileewe lfeoluwa Co Educational Grammar School, to wa niluu Osogbo, pa pẹlu bi awọn eeyan kan ti wọn fura si gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ okunkun ṣe ya wọ ileewe naa pẹlu awọn ohun ija oloro lọwọ.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Yemisi Ọpalọla, ṣalaye fawọn oniroyin pe awọn ọdọmọkunrin bii ogun ni wọn ya wọ ileewe naa pẹlu ada atawọn ohun ija olori mi-in lati da wahala silẹ.

Opalola sọ pe, “Awọn ọga ileewe Ifẹolu, niluu Osogbo, ni wọn ran ni si wa pe awọn ọdọ kan ti wọn to ogun ya wọ ileewe naa pẹlu ada atawọn ohun ija oloro mi-in lọwọ. Loju-ẹsẹ ti a gbọ pe ipe pajawiri yii naa lati ran awọn ẹṣọ agbofinro wa lọ sibẹ. Nibẹ naa ni ọwọ ti tẹ ọkunrin kan ti wọn ti ṣa ladaa lori ati ni apa. Nibẹ naa ni wọn ti sare gbe e lọ si ileewosan, Oṣogbo Central Hospital, fun itọju to peye.”

Ṣa o, Oludari agba feto ẹkọ nipinlẹ Ọṣun, Kẹhinde Ọlaniyan, ti ṣalaye idi ti wọn fi sare ti ileewe ọhun pa. O ni, “Ki wahala ti awọn ọdọ ti wọn pe ni ọmọ ẹgbẹ okunkun, ti wọn n pera wọn ni ọmọleewe ọhun da silẹ ma lọọ burẹkẹ ju bẹẹ lọ lo jẹ ka tete paṣẹ pe ki wọn ti ileewe ọhun pa.

Oludari agba feto ẹkọ l’Ọṣun ti waa rọ awọn obi ati alagbatọ pe ki kaluku mu ọmọ ẹ sabẹ titi ti ikede mi-in yoo fi waye pe ki wọn pada sileewe ọhun.

Bakan naa ni ileeṣẹ eto ẹkọ nipinlẹ naa ti ṣeleri lati ṣawari awọn janduku to kọ lu ileewe naa, ti wọn yoo si fojun wina ofin.

Leave a Reply