Nitori awọn ti wọn pa ni Lẹki, Fani Kayọde sọrọ buruku si Tinubu

Aderounmu Kazeem

Minista feto ọkọ ofurufu tẹlẹ lorilẹ-ede yii, Ọgbẹni Fẹmi-Fani Kayọde ti ṣapejuwe Aṣiwaju Bọla Tinubu gẹgẹ bi ika ati ọdaju eniyan, to fẹran agbara oṣelu ju ẹmi ẹda ẹgbẹ lọ.

Ọkunrin ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP yii sọ pe ọ jẹ ohun to baayan ninu jẹ wi pe ọwọ yẹpẹrẹ ni Tinubu fi mu bi awọn eeyan ṣe padanu ẹmi wọn nigba tawọn ṣoja kan kọlu wọn ni too-geeti Lẹkki, l’Ekoo.

O ni, “Iṣọwọ dahun ibeere nigba tawọn oniroyin bi ẹ nipa ohun to ṣẹlẹ ni Lẹkki fi ẹ han gẹgẹ bii ọdaju eeyan ti ko laanu kan bayii loju. Wọn n sọrọ to la ẹmi awọn ọdọ kan lọ, niṣẹ ni wọn mu un bii ere, ti o tun n ṣawada wi pe o ko kuro lorilẹ-ede yii rara nitori iwọ gan an ni wọn n pe ni Jagaban

“Ohun to tun buru ju ni bo ṣe sọ pe ko sẹni to ku ni Lẹkki nibi tawọn ṣoja ti rọjo ibọn lu awọn ọmọ ọlọmọ. Iru eeyan gidi wo lo n sọru ẹ lọrọ. Bakan naa ni ko si ọrọ ibanikẹdun fun awọn eeyan ti nnkan ṣẹlẹ, ṣugbọn to jẹ pe niṣe lo tun n sọ pe o yẹ ki iwadii to yẹ waye lori ohun to ṣẹlẹ ni Lẹkki, nitori ko si ẹri to fidi ẹ mulẹ wi pe ẹni kan bayii lo ṣofo ẹmi.”

Fani Kayọde sọ pe Bọla Tinubu ko ṣẹṣẹ maa ṣe e, ati pe bo ṣe ṣe gan an niyẹn nigba ti awọn Fulani pa ọmọ Alagba Reuben Fasoranti, to jẹ pe awọn ọrọ to n jade lẹnu ẹ, o fi i han wi pe tawọn apaayan Fulani yẹn gan an lo n ṣe.

O ni,“Mo mọ wi pe nitori ti ọ fẹẹ di aarẹ orilẹ-ede yii lo ṣe n ṣe gbogbo nnkan wọnyi, ṣugbọn mo fẹẹ fi da ẹ loju wi pe, o ko ni ibi ti o n lọ rara. Wo o daadaa, ko le ṣee ṣe.”

 

Leave a Reply