Nitori ayẹyẹ ọdun Hijirah, ijọba Ọṣun kede isinmi lọla  

Florence, Babaṣọla, Oṣogbo

Ogunjọ, oṣu yii, ti i ṣe ọla, Ọjọbọ, ni ijọba ipinlẹ Ọṣun kede gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ lati ṣe ayajọ ibẹrẹ ọdun tuntun awọn Musulumi.

Kọmiṣanna feto Iroyin ati Ilanilọyẹ nipinlẹ naa, Aarabinrin Funkẹ Ẹgtbẹmọde, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to fi sita ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii. Nibẹ lo ti ṣalaye pe ‘Ijọba ti kede ogunjọ, oṣu yii, gẹgẹ bii ọjọ iṣinmi lẹnu iṣẹ lati fun awọn Musulumi lanfaani lati ṣe ayajọ ọdun tuntun Hijirah 1442 AH. Ṣugbọn eyi ko faaye gba ikojọpọ ero pupọ tabi apejọpọ yoowu ko lẹ jẹ. Bakan naa lo ṣe pataki pe ki awọn araalu tẹle ilana ijọba lori arun Korona to wa nita gẹgẹ bi ijọba ṣe la a kalẹ.’’

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanlelogun, lo ni gbogbo oṣiṣẹ gbọdọ pada sẹnu iṣẹ.

Leave a Reply