Nitori Baba Ijẹṣa, babalawo kan ṣepe fun Iyabọ Ojo

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bi ẹnikan ba wa to loun mọ ibi ti ọrọ Baba Ijẹṣa yii yoo pari si, irọ ni tọhun n pa. Idi ni pe ojumọ kan, wahala kan, ni latigba ti ọrọ yii ti bẹrẹ, paapaa fun Iyabọ Ojo to kọkọ gbe agbada ọrọ naa kari.

Babalawo kan lo tun jade wayi to ni iku iya ni oṣere tiata yii yoo ku nitori ọrọ Ijẹṣa, n ni Iyabọ naa ba da ayajọ inu Bibeli bolẹ, lo ni oun ki yoo ku iku kiku kan bi ko ṣe yiye.

HRH Ọba Ọmọwe Augustine Bọla Adegunloye (Ẹgbeji Oloogun ilẹ Naijiria) lorukọ babalawo naa ti akọroyin kan fọrọ wa lẹnu wo nipa bi Iyabọ Ojo ṣe ni afi ki Baba Ijẹṣa jiya ẹṣẹ lori ọmọde ti wọn lo fipa ṣe kinni fun, ni baba yii ba bẹrẹ si i ṣalaye bo ṣe jẹ pe ẹyin Iyabọ Ojo ko le daa laye yii. Niṣe lo ni kawọn eeyan maa wo atubọtan Iyabọ, o ni yoo rare, yoo jiya, yoo si waa ku iku buruku gbẹyin aye rẹ ni.

Egbeji Oloogun ilẹ Naijiria sọ pe, ” Iyabọ Ojo yoo kuku iya. Ki i ṣe pe mo n gbe lẹyin Baba Ijẹṣa o, ṣugbọn Iyabọ Ojo ti ba ọpọlọpọ ọkunrin lo pọ, ti idajọ Ọlọrun ba si de, o maa rare, o dẹ maa ku, ẹyin ẹ maa wo o.

“Lati ibi si Abuja, ki lo n wa kiri, abẹ lo n ta kiri. Baba Ijẹṣa ko ṣẹtọ foun atobinrin keji yẹn to ni wọn ṣe ba a lorukọ jẹ. Ọlọrun dẹ maa ba ti Iyabọ Ojo naa jẹ, ẹ maa wo o.

“Ohun to ṣe loju ọmọ ẹ lọmọ naa ṣe, ọmọ ọhun ko dẹ ki i ṣe ọmọ ẹ, to ba jẹ ọmọ bibi inu ẹ ni, ko ni i gbe e jade bẹẹ, nitori o maa mọ pe ọmọ naa ko ni i rọkọ fẹ. Afi ko lọọ yipada ki nnkan le daa fun un, ko dẹ le yipada bo ṣe wa yẹn, nitori ba a ṣe n sọrọ yii, ọkunrin bii mẹrin lo ti ba ladehun to fẹẹ lọọ ba, abẹ rẹ ti da bii rọba, obinrin to ba ti fẹran ibalopọ, bi abẹ wọn ṣe maa n da bii rọba niyẹn’’

Nipa awọn oṣere tiata obinrin ti wọn n kọle nla ti wọn n ra mọto dẹndẹ, to si jẹ awọn ọkunrin wọn ko rọwọ họri, baba agbalagba to ni Ẹgbẹji loun yii sọ pe to ba ti jẹ abẹ wọn ni wọn ta ti wọn fi ko o jọ, o ni wọn maa jiya gidi gbẹyin ni.

Baba naa sọ pe mọto ti iya wọn ko ra, ile ti baba wọn ko kọ ti wọn fabẹ kọ ko le mu daadaa wa, o ni ogidi iya naa ni wọn yoo fi jẹ gbẹyin, kawọn aye maa woran wọn.

Leave a Reply