Nitori bawọn akẹkọọ ṣe fẹhonu han lori iku ọkan ninu wọn, awọn alaṣẹ Fasiti Ifẹ ti ileewe naa pa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Awọn alaṣẹ ileewe giga Fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ University, Ileefẹ, ti paṣẹ pe ki awọn akẹkọọ kuro ninu ọgba ileewe naa, o pẹ tan, aago mejila ọsan Satide, ki alaafia le pada sagbegbe ibẹ.

Igbesẹ yii ko ṣẹyin bi awọn akẹkọọ ṣe fọn soju titi lati idaji ọjọ Ẹti, Furaidee, lati fẹhonu han lori iku ọkan lara wọn, Aishat Adeṣina, to wa ni ipele ọdun kẹrin ni ẹka ti wọn ti n kẹkọọ nipa ede ilẹ-okeere (Foreign Languages)

Ohun ti awọn akẹkọọ naa ti wọn ko jẹ ki awọn ọkọ raaye gba oju-ọna Ifẹ si Ibadan sọ ni pe aikọbiara si itọju Aishat nileewosan to jẹ ti ileewe naa lo fa a to fi ku.

Atẹjade kan ti Aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ati Akọwe rẹ, Ọlayiwọla Festus ati Ọdẹwale Damilare, sọ pe awọn nọọsi ti wọn wa nibẹ kọ lati ṣayẹwo to tọ fun Aishat ti wọn fi sọ pe ko maa lọ sileewosan Seventh Day, nibi to ku si lọgbọnjọ, oṣu kẹsan-an, ọdun yii.

Wọn ke si awọn alaṣẹ fasiti ọhun lati ṣewadii iṣẹlẹ naa daadaa, ki wọn si fi imu awọn oṣiṣẹ ti ajere iwa buburu naa ba ṣẹ mọ lori nileewosan ọhun jofin.

Awọn mejeeji ṣalaye pe ibanujẹ nla ni iku akẹkọọ-binrin naa jẹ fun Fasiti OAU, fun ẹka to wa, fun awọn obi rẹ ati fun gbogbo awọn akẹkọọ patapata.

Wọn fi kun ọrọ wọn pe awọn ko gbọdọ kawọ gbera lori rẹ rara, awọn ni lati fọn sita fẹhonu han, ki iru rẹ ma baa ṣẹlẹ mọ.

Ṣugbọn nigba to n sọrọ, Alukoro fasiti naa, Abiọdun Ọlanrewaju, ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ ileewosan naa gbiyanju ipa wọn lori ọrọ Aishat.

O ni lọjọ kejidinlọgbọn lọmọbinrin naa kọkọ lọ sileewosan fun itọju, lẹyin ti wọn ṣayẹwo ara rẹ ni wọn fun un nitọju to tọ, ti wọn si sọ pe ko pada wa.

Nigba to pada debẹ laaarọ ọgbọnjọ, oṣu kẹsan an, ti wọn tun ṣayẹwo fun un ni wọn sọ pe ko maa lọ sileewosan Seventh Day, nibi to pada ku si.

Ọlarewaju fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo ipa lawọn alaṣẹ ṣa lati le jẹ ki awọn akẹkọọ na suuru si ọrọ naa, nigba ti wọn ko si gba ni ileewe paṣẹ pe ki gbogbo wọn maa lọ sile obi wọn.

Leave a Reply