Awọn kọmiṣanna fun eto ọgbin lawọn ipinlẹ mẹfẹẹfa nilẹ Yoruba, Ọyọ, Ondo, Ekiti, Ogun, Ọṣun ati Eko n ṣe ipade pajawiri kan lọwọlọwọ bayii lori ẹrọ ayelujara.
Lara awọn ti wọn darapọ mọ ipade yii pẹlu wọn ni ileeṣẹ eto ọgbin nilẹ Yoruba, ‘South WestAgricultural Company’ (SWACO). Bakan naa ni ileeṣẹ to wa fun idagbasoke awọn ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba, ‘Development Agenda for Western Nigeria’ (DAWN) naa darapọ mọ wọn nibi ipade yii.
Koko ipade naa gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ ni lati jiroro lori bi ounjẹ yoo ṣe sun araalu bọ ni ilẹ Yoruba, paapaa ju lọ pẹlu bi awọn Hausa ṣe paṣẹ pe ki wọn ma gbe awọn ohun jijẹ wa silẹ Yoruba mọ.
Tẹ o ba gbagbe, lẹyin ija Ṣhaṣha, niluu Ibadan, ni ẹgbẹ awọn to n ta maaluu atawọn ti wọn n ta ounjẹ pepade, ti wọn si ni awọn ko ni i gbe ounjẹ wa si ilẹ Yoruba mọ. Bẹẹ ni wọn beere owo nla lọwọ ijọba apapọ ki wọn too le maa ko ọja wa si ilẹ Yoruba.
Awọn ohun jijẹ bii tomato, iṣu, alubọsa ati ata lo ti wọn latigba naa pẹlu bo ṣe jẹ pe awọn orileede bii Niger, Cameroon ni wọn ni wọn n ko awọn ounjẹ naa lọ bayii.