Nitori bi arun Koronafairọọsi ṣe n gbilẹ si i, ijọba Ekiti ṣofin konilegbele

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ijọba ipinlẹ Ekiti ti ṣe ikede konilegbele lati aago mẹjọ alẹ si mẹfa aarọ, bẹrẹ lati ọjọ Aje, Mọnde, ọse yii, pẹlu bi arun Koronafairọọsi ṣe n fojoojumọ pọ si i.

Ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna feto iroyin, Ọnarebu Akinbọwale Ọmọle, fọwọ si lọjọ Aiku,  Sannde, lo ti sọ pe igbesẹ ọhun waye lati dena itankalẹ Korona nitori ipele keji yii lagbara ju eyi to wa tẹlẹ lọ.

Atẹjade naa sọ ọ di mimọ pe eto konilegbe ọhun yoo mulẹ gidi, awọn ti ofin si gba laaye lati rin nikan ni ko ni i ko sọwọ awọn agbofinro.

Bakan naa lo ni ofin ṣi de awọn ile ijọsin lati maa ṣe isin meji lọjọ Ẹti, Abamẹta ati Aiku, bẹẹ ni ki wọn maa tẹle ofin imọtoto nipa ipese omi iṣanwọ ati ọṣẹ, lilo ibomu ati titakete sira ẹni.

Ọmọle ni Gomina Kayọde Fayẹmi gbe igbesẹ tuntun yii nitori bi ipele keji Koronafairọọsi ṣe n pa awọn eeyan kaakiri agbaye, bẹẹ lo rọ awọn olori ilu ati agbegbe lati ran ijọba lọwọ lori lile arun ọhun wọlẹ.

Leave a Reply