Nitori bi Iyalọja Folaṣade Tinubu-Ojo ṣe ti ọja wọn pa fun odidi ọjọ mẹrinla, awọn ọlọja Oyingbo fẹhonu han

Jọkẹ Amọri

Tọkunrin-tobinrin, tọmọde-tagba, ni wọn tu jade laaarọ kutu Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lati fẹhonu han ta ko titi ti Iyalọja General, Fọlaṣade Tinubu-Ojo ti ọja naa pa lati bii ọjọ mẹrinla sẹyin.

Akọle oriṣiiriṣii ni awọn eeyan naa gbe lọwọ bii ‘Ẹ ba wa bẹ Tinubu Ojo ko fi wa silẹ o’ A ko fẹẹ wa labẹ Iyalọja General mọ’, Iya yii ti pọ ju, ẹyin ọmọ Naijiria, ẹ gba wa lọwọ Fọlaṣade Tinubu-Ojo’ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ohun ti awọn ọlọja yii ni o fa wahala gẹgẹ bi diẹ ninu wọn to ba ALAROYE sọrọ nigba ti akọroyin wa ṣabẹwo sibẹ ni pe ni ọjọ mẹrinla sẹyin ni iyalọja naa wa sinu ọja yii, o si ṣabẹwo si awọn ọja igbalode to wa nibẹ. Sugbọn nigba to sọ kalẹ ni ile ori oke naa lo ni aja keji ọja naa dọti.

Awọn eeyan naa ni gbogbo alaye awọn pe isalẹ lawọn ti n taja, awọn ko mọ ohunkohun nipa ohun to n lọ loke ko so eeso rere.

Awọn ọlọja ni afi bi Iyalọja General ṣe paṣẹ pe ki wọn ti ọja naa pa. Wọn ni awada lawọn kọkọ pe ọrọ naa, afi bi awọn ti wọn ran ṣe ti ọja naa, ti ọpọ awọn mi-in ko ti de, ti ọpọ awọn to si wa nibẹ ko raaye ko ọpọlọpọ ọja wọn jade.

Wọn ni latigba naa lawọn ti n bẹ ẹ, tawọn si ti gbe igbesẹ lati gba awọn eeyan ti yoo maa tun ọja naa ṣe yatọ si awọn ọlọja to maa n gba a. Wọn ni gbogbo ẹbẹ tawọn bẹ ọmọ olori oloṣelu ilu Eko naa lo ja si pabo.

Nigba to si ya lo ni afi ki awọn san miliọnu marun-un Naira owo itanran koun too le ṣi ọja naa pada.

‘Gbogbo ọja wa lo ti bajẹ. Igbin ni o, ẹgusi, ẹfọ ati oriṣiiriṣii ohun jijẹ lo ti bajẹ sinu ile. Bi a ko ba si de ọja yii, a ko le jẹun. Ẹyin ni mo n ta, bii kireeti ẹyin aadọta lo wa ninu ṣọọbu. Awin ni mo maa n gba ẹyin yii, ti mo ba ta a tan ni mo maa n da owo pada. Ṣugbọn awọn eeyan naa ko wo ti ewú to wa lori mi ti wọn fi ti ọja yii pa. Ẹbẹ ni mo n bẹ Fọlaṣade Tinubu-Ojo ko dari gbogbo aṣiṣe wa ji wa, ko ba wa ṣi ọja naa.’’ Bẹẹ ni iya agba yii sọ.

 

Leave a Reply