Nitori bi imaamu meji ṣe ku tẹle’ra wọn, ijọba Ọṣun ti mọṣalaaṣi ilu Iniṣa pa

Florence Babaṣọla

Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti paṣẹ pe ki mọṣalaaṣi nla inu Iniṣa, nijọba ibilẹ Odo-Ọtin, Inisa Town Central Mosque, wa ni titi titi ti wahala ọrọ oye imaamu ibẹ yoo fi niyanju.

Ninu atẹjade kan ti Igbakeji olori awọn oṣiṣẹ lọọfiisi gomina, Abdullahi Binuyọ, fi sita ṣalaye pe ko gbọdọ si ipejọpọ adura Yidi Itunu aawẹ nibẹ lati le dena wahala to le fẹẹ ṣẹlẹ nibẹ.

Binuyọ ṣalaye pe ijọba ti ko awọn agbofinro lọ sibẹ lati ri i pe ko sẹni to tasẹ agẹrẹ si aṣẹ naa, titipa ni mọṣalaaṣi naa yoo si wa titi ti awọn Musulumi ilu naa yoo fi forikori lori ọrọ ẹni ti yoo jẹ Imaamu agba wọn.

Iwadii ALAROYE fi han pe wahala naa bẹrẹ lẹyin ti imaamu agba tẹlẹ fun ilu naa ku, lẹyin oṣu diẹ ti wọn kede imaamu mi-in loun naa tun ku, bẹẹ lẹlomi-in to tun jẹ lẹyin onitọhun naa jade laye lojiji.

Lasiko ti Eesa ilu naa tẹlẹ, Oloye Enoch Ajiboso, n ba wọn yanju wahala naa laafin Oluniṣa tilu Iniṣa loṣu kejila, ọdun to kọja, loun naa ṣubu lulẹ, to si gbabẹ ku.

Loṣu kin-in-ni, ọdun yii, lawọn abala kan yan imaamu agba tuntun, nigba ti abala keji tun fi ẹlomi-in jẹ, latigba naa ni wọn si ti ni imaamu agba meji niluu naa, ti onikalulu si n ṣe tiẹ lọtọọtọ.

Lati le dena wahala to le ṣẹlẹ ni Yidi lọjọ ayẹyẹ ọdun Itunu aawẹ la gbọ pe o mu kijọba kede pe kẹnikankan ninu wọn ma ṣe lọ si Yidi titi ti wọn yoo fi yanju ọrọ naa.

Leave a Reply