‘‘Nitori bi Korona ṣe n gbilẹ si i, o ṣee ṣe kijọba kede ofin konilegbele’’

Laarin ọsẹ kan, ajọ to n gbogun ti itankalẹ arun Koronafairọọsi ti sọ pe o le ni eeyan mẹtalelọgbọn ti arun ọhun tun ti kọ lu bayii, ati pe tawọn eeyan orilẹ-ede yii ko ba ṣọra, o ṣee ṣe ki ofin konilegbele tun waye lẹẹkan si i.

Alakooso gbogboo-gbo fun ajọ to n gbogun ti itakanlẹ arun ọhun, Dokita Sani Aliyu, ti sọ pe ọna kan pataki ti awọn araalu le gba ti wọn ko ba fẹ ki ijọba tun kede ofin konilegbele ni kawọn eeyan bẹrẹ si i tẹle ofin ati ilana ijọba lati fopin si itankalẹ arun buruku yii.

Yatọ si awọn araalu ti wọn ko tun fẹẹ jokoo sile kan-an-pa mọ, bẹẹ lawọn olokoowo atawọn onileeṣẹ nla nla paapaa naa ti n rawọ rasẹ si ijọba bayii ko ma tun gbe iru igbesẹ bẹẹ lasiko yii, nitori idaamu nla ti yoo ko ba ọrọ aje.

Lori eto kan ni Dokita Aliyu ti sọrọ yii lori tẹlifiṣan pe, “Ti awọn eeyan ko ba fẹẹ jokoo sile kan-an-pa, wọn gbọdọ maa wọ ibomu wọn, ki wọn si yẹra fun ibi ti ọpọ ero ba pọ si. Awọn eeyan gbọdọ maa fọwọ wọn deede, ki ẹ si maa pa awọn ofin yooku to le dena itankalẹ arun Koro mọ.

“Awọn orilẹ-ede kan wa ti wọn ti kapa itankalẹ arun yii nitori pe wọn n tẹle ofin ati ilana ti ijọba gbe kalẹ. Loootọ ni o le ma rọrun, ṣugbọn o ṣi dara ju ki ijọba kede ofin konilegbele lọ. Laarin ọsẹ kan pere, eeyan mẹtalelọgbọn lo ti ku, ka ni wọn ba n pa ofin yẹn mọ ni, iru iṣẹlẹ bẹẹ ko ni i waye. Bakan naa lo jẹ ohun iyalẹnu bi ẹgbẹrun mẹfa eeyan tun ṣe ko o laarin ọsẹ kan pere.”

Dokita Aliyu, ti sọ pe loootọ ni aisan ọhun wa, ati pe ẹnikẹni to ba n sọ pe irọ ni, bii ẹni ti ko mọ ohun to n ṣe ni.

Ṣiwaju si i, o ni titi ipari oṣu yii ni abẹrẹ ajẹsara fun arun buruku yii yoo de si Naijiria, ati pe nigba to ba maa fi to oṣu mẹfa, pupọ ninu awọn orilẹ-ede lagbaye ni wọn yoo maa beere fun iwe-ẹri mo yege, mi o ni arun koro lara, ki wọn too le gba ẹnikẹni laaye lati wa sorilẹ-ede wọn. Nibẹ yẹn gan-an ni yoo ti ṣoro fawọn ti wọn n bẹru lati gba abẹrẹ lati lọ soke okun, paapaa awọn to fẹẹ l̀ọ fun Umurah, Hajj, tabi Jerusalẹẹmu, ti wọn n ṣagidi pe awọn ko ni i gba abẹrẹ ajẹsara ọhun.

Ṣa o, Minisita fun eto iroyin, Alhaji Lai Mohammed, ti sọ pe ki awọn araalu fọkan wọn balẹ, ijọba apapọ ko ni i kede ofin konilegbele, ṣugbọn ki kaluku gbiyanju lati maa pa gbogbo ofin ati ilana tijọba la silẹ lati fopin si itankalẹ arun ọhun mọ.

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Ile-ẹjọ to ga ju lọ da ẹjọ Buhari ti Malami pe ta ko ofin eto idibo nu

Faith Adebọla Ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa ti wọgi le ẹjọ ti Aarẹ …

Leave a Reply

//lephaush.net/4/4998019
%d bloggers like this: