Nitori bi korona ṣe pa ọkan ninu wọn, awọn aṣofin Eko bẹrẹ ayẹwo

 

Latari aṣẹ tileegbimọ aṣofin Eko  pa pa pe ki gbogbo awọn ọmọ ile aṣofin naa, atawọn oṣiṣẹ wọn latoke delẹ lọọ ṣe ayẹwo arun Korona lati mọ ipo ti onikaluku wọn wa, awọn aṣofin ọhun ti n lọ fun ayẹwo wọn lọkọọkan.

Igbesẹ yii ni wọn lo pọn dandan latari bi kokoro aṣekupani naa ṣe n ṣọṣẹ nipinlẹ ọhun, leyii to ti yọri si pipadanu awọn aṣofin meji laarin ọsẹ meji aabọ sira wọn.

Ọnarebu Temitọpẹ Adewale to n ṣoju agbegbe idibo Ifakọ Ijaye kin-in-ni sọ ninu atẹjade kan pe abajade esi ayẹwo COVID-19 toun ṣe fi han pe oun ko ni arun naa lara.

Yatọ si pe awọn aṣofin naa atawọn oṣiṣẹ wọn lọọ ṣayẹwo, AKEDE AGBAYE tun gbọ pe wọn ti paṣẹ pe ki wọn fin kẹmika si gbogbo ọfiisi ati ile awọn aṣofin naa, tori oju lalakan fi n ṣọri, igbesẹ naa si ti bẹrẹ laarin ọsẹ to kọja.

Aipẹ yii ni arun buruku naa gbọna ẹburu pa ọkan lara awọn aṣofin ọhun, Ọnarebu Tunde Buraimoh, to n ṣoju agbegbe idibo Kosọfẹ Keji lojiji, ọrẹ timọtimọ si ni Buraimoh pẹlu aṣofin Oloogbe Sẹnetọ Adebayọ Ọshinọwọ ti wọn tun un pe ni Pepperito, to n ṣoju ẹkun idibo Ila-Oorun Eko nileegbimọ aṣofin agba l’Abuja, ẹni tiku yọwọ ẹ lawo lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu to kọja, lai ro tẹlẹ.

Ababọ ayẹwo iku ọhun ni wọn ni ko ṣẹyin COVID-19 to gbaye kan bayii, eyi si ti da ibẹrubojo sọkan awọn aṣofin atawọn araalu, tori ewu akoran arun buruku naa.

 

Leave a Reply