Nitori bi nnnkan ṣe ri nita, Portable olorin pin ounjẹ fawọn eeyan

Jọkẹ Amọri

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ ni ko fẹran imura ati awọn iwa kan to maa n hu, ṣugbọn pẹlu rẹ naa, adura ni awọn eeyan n ṣe fun ọmọkunrin olorin taka-sufee nni, Habeeb Okikiọla, ti gbogbo eeyan mọ si Portable tabi Zazuu. Ohun ti ọpọ ko lero si ọmọkunrin naa lo ṣe laipẹ yii. Niṣe ni Portable to maa n saabaa dasa ‘wahala wahala’ ko ọpolọpọ ounjẹ to ti di sinu ọra lọkọọkan, to si gba igboro lọ, lo ba bẹrẹ si i pin in fun awọn eeyan.

Iyalẹnu lọrọ naa jẹ fun ọpọlọpọ nitori wọn ko reti iru nnkan yii lọdọ onkọrin ti ara rẹ ki i balẹ naa. Niṣẹ ni awọn eeyan ṣuru bo ounjẹ yii, ti wọn bẹrẹ si i gba a, ti inu wọn si n dun. Bẹẹ ni ọpọlọpọ eeyan si n rọjo adura le e lori.

Awọn kan ni asiko ti ọmọkunrin yii ṣẹ kinni naa si daa pupọ. Nigba ti ko si owo, ti epo bẹntiroolu wọn, ti ọpọ ko si rowo gba ni banki lati fi ra awọn ohun ti wọn le jẹ. Wọn ni ti gbogbo awọn ti Ọlọrun ṣẹgi ọla fun lawujọ ba le ṣe eleyii, nnkan yoo rọrun diẹ si i fun awọn mẹkunnu.

Ninu fidio to gbe jade to fi ṣafihan bo ṣe n pin ounjẹ naa lo kọ ọ si bayii pe, ‘‘Zazuu, ẹ yee duro ki nnkan ṣẹlẹ kẹ ẹ too ṣe nnkan, ẹyin naa ẹ lọ sita lati mu nnkan ṣẹlẹ. Ẹni to ba maa ran yan lọwọ ko ni i fun tọhun ni wahala ko too ṣe bẹẹ. A maa n ṣalabaapade awọn eeyan fun idi kan tabi omi-in ni, wọn le jẹ orisun ibukun fun wa tabi ki wọn jẹ ẹkọ fun wa. Igboro ti gbajọba bayii o. Olorin ika Afrika, idaamu adugbo yin…’’

Bẹẹ ni oṣere yii kọ ọ sabẹ fidio to gbe jade naa. Inu ọpọ awọn ololufẹ rẹ lo dun si igbesẹ to gbe ọhun, bẹẹ ni wọn ti n ki i ti wọn si n sa a, ti wọn n gbadura fun un pe igbesẹ to daa lo gbe.

Eyi ni diẹ lara ọrọ ti awọn ololufẹ rẹ kọ sabẹ fidio naa.

Ẹnikan to pe ara rẹ ni kopa.respect sọ pe ‘Ẹnikẹni to ba n wa iṣubu rẹ , ohun lo maa ṣubu…’

‘Ṣe Portable ti ẹ n sọ pe ko ni i pe ọdun kan kọ niyi, ẹ maa mura yin ṣere’.

‘Portable gbọn gan-an ni o, ṣugbọn awọn kan ro pe ko gbọn, mo gboṣuba fun ọ o.’

Ẹnikan kọ tiẹ pe, ‘Ọmọ ọlọpẹ, ọmọ ologo, mo dupẹ lọwọ rẹ pe o maa n ranti awọn ọmọ adugbo, loootọ ni o mọ awọn ohun ti iwọ naa koju nigba to o wa nibẹ. O o ni i kuna, o o ni i ṣubu’.

Bẹ o ba gbagbe, oṣere yii lo de ara rẹ mọ inu posi lasiko kan to lọọ ṣere ni Ikẹja. Laipẹ yii lo si pariwo iyawo to bimọ fun un sita, o ni obinrin naa n yan ale. Gbangba lo si gbe itakurọsọ to waye laarin obinrin naa ati ale rẹ sita.

Leave a Reply