Nitori bi ọmọọṣẹ rẹ kan ṣe ni aru korona, Sanwoolu bẹrẹ igbele 

Jide Alabi

Nitori bi arun korona ṣe kọ lu ọkan ninu awọn ọmọọṣẹ rẹ, Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti wa ni iyasọtọ bayii lati dena titan arun naa kaakiri.

Kọmiṣanna fun eto ilera, Ọjọgbọn Akin Abayọmi, lo sọ eleyii di mimọ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Ẹti, Furaidee, ọse yii.

O ni eyi ṣe pataki nitori bi ọkan ninu awọn ọmọoṣẹ rẹ ṣe ni arun naa ni lọjọ kẹwaa, oṣu yii, iyẹn Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii..

O fi kun un pe awọn yoo ṣayẹwo fun gomina atawọn ọmọọṣẹ rẹ, bẹẹ ni gomina yoo si wa ni igbele titi ti esi ayẹwo yii yoo fi jade.

O waa rọ awọn araalu lati mu ofin imọtoto ni pataki, ki wọn si pa gbogbo ilana ofin korona mọ pẹlu bi aisan naa ṣe tun fẹẹ maa tan kalẹ.

Leave a Reply