Nitori bi wọn ṣe na Kano Pillars, Makinde fun Shooting Stars ni miliọnu kan Naira

Ojo James

Ojo owo ti rọ fun awọn agbabọọlu ilu Ibadan, Shooting Stars Sports Club ti gbogbo eeyan mọ si (3SC) tabi Oluyọle Warriors, pẹlu bi Gomina ipinlẹ naa, Ẹnjinnia

Seyi Makinde ṣe fun wọn ni miliọnu kan Naira pẹlu bi wọn ṣe na awọn ẹlẹgbẹ wọn lati ipinlẹ Kano, Kano Pillars, ni ami-ayo kan si odo.

Titi ti idije to waye ni papa iṣere Lekan Salami naa fi pari ni ikọ mejeeji fi n ja raburabu lati gba bọọlu sile ara wọn. Nigba to di bii iṣẹju mẹrinla ti wọn ti n gba bọọlu naa to bẹrẹ ni deede aago meje alẹ ni agbabọọlu Oluyọle Warrior gẹgẹ bi wọn ṣe tun maa n pe kilọọbu Ibadan naa, Ezeala Uche, ju bọọlu kan sinu awọn Kano Pillars. N lariwo ba sọ

Latigba naa ni awọn Shootings ti di ile wọn pinpin, ti wọn ko si gba awọn alejo wọn laaye lati le wọbẹ debi ti wọn yoo ju bọọlu sibẹ. Bo tilẹ jẹ pe awọn agbabọọlu naa ja raburabu.

Pẹlu ami ayo kan si odo ti wọn gba yii, wọn gba ami mẹta, eyi to mu wọn sun soke diẹ lori tabili.

Gomina Ṣeyi Makinde, ẹni to wa ni papa iṣere ti bọọlu naa ti waye ko le pa idunnu rẹ mọra, pẹlu bi awọn Oluyọle Warriors ṣe gbegba oroke yii. O ni inu oun dun lati wo ifẹsẹwọnsẹ naa, pe oun si n foju sọna fun aṣeyọri mi-in latọdọ awọn agbabọọlu yii.

Miliọnu kan Naira lo fun wọn lati fi ṣe koriya fun wọn, bẹẹ lo si fun ikọ Kano Pillars naa ni miliọnu kan Naira.

Lẹyin ifigagbagba naa, awọn agbabọọlu ti ko le pa idunnu wọn mọra naa sọ pe awọn fun idije naa ni gbogbo ohun to gba lati le dẹrin-in pẹẹkẹ awọn ololufẹ awọn nitori o pẹ diẹ tawọn ti ṣe bẹẹ gbẹyin.  

Leave a Reply