Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ko sẹni to ti i mọ ẹni ti wọn jẹ o, iyẹn awọn kan ti wọn da Kabiyesi Ayinde Ọdetọla, Olu ti Agodo, l’Ewekoro, nipinlẹ Ogun, lọna lọjọ Aje ọsẹ yii. Ti wọn pa a sinu mọto ayọkẹlẹ rẹ, ti wọn si tun dana sun oku ọba naa mọbẹ gburugburu!
Gẹgẹ b’Alaroye ṣe gbọ, iṣẹlẹ ibanujẹ yii waye ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 yii. Bi Kabiyesi ṣe n dasẹ wọlu ni awọn eeyan naa bo o, ti wọn pa a sinu mọto, ti wọn tun dana sun oku naa kọja idanimọ.
Ohun tawọn eeyan tiẹ kọkọ n sọ ni pe ki i ṣe Olu Agodo nikan lawọn eeyan naa dana sun, wọn ni wọn tun pa awọn eeyan mẹta kan ti wọn jọ de ilu naa.
Awọn mi-in sọ pe awọn ọmọ Kabiyesi lo wa pẹlu ẹ ninu mọto lasiko naa, pe wọn si pa wọn pẹlu. Ṣugbọn gbogbo eyi ni Alukoro ọlọpaa Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ pe irọ ni.
Alukoro ọlọpaa sọ pe Kabiyesi nikan ni awọn eeyan ibi naa dana sun lẹyin ti wọn pa a tan.
O ni CP Lanre Bankọle ti i ṣe ọga awọn ti lọ sibi iṣẹlẹ naa, o si ri i pe ọba alaye naa nikan ni wọn pa. Oyeyẹmi fi kun un pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ lori iṣẹlẹ yii, otitọ yoo si foju han laipẹ.
Koda, awọn araalu Agodo ti sa lọ tan bayii gẹgẹ b’Oyeyẹmi ṣe wi, ibẹru lo mu wọn sa kuro niluu, nigba ti ọba alaye dẹni ti wọn n pa lojumọmọ, ti wọn tun n dana sun un.
Lori ohun to fa wahala yii, a gbọ pe latilẹ ni ikunsinu ti wa lori ẹni ti wọn fi jẹ Olu Agodo yii. Awọn kan ko fẹ ki wọn fi Ọba Ọdẹtọla jẹ ẹ lati ibẹrẹ pẹpẹ, idi si ni pe wọn ni ọmọ Ake ni.
Awọn to n binu sọ pe ko ṣee ṣe ki ara Ake waa jọba lọdọ awọn ti i ṣe Owu. Wọn ni Ake lọmọ abi l’Ake ti i jọba, ọmọ Owu aa si joye nile Owu.
Latigba naa ni wahala ti wa. Koda, ko ti i pẹ tawọn kan pa aburo Kabiyesi Ọdẹtọla yii, wọn ṣa ọkunrin naa wẹlẹwẹlẹ lori ọrọ ọlọbade yii naa ni. Awọn ẹbi naa ko ti i bọ ninu ibanujẹ iyẹn to tun fi di pe awọn kan tun pa odidi ọba ilu lojiji bayii.
Ọpọ eeyan lo n koro oju si iwa tawọn to pa Ọba Ayinde Ọdẹtọla hu, wọn ni iru iku ti wọn fi pa a yii buru jai, ko tiẹ waa si ọ̀wọ̀, ko si apọnle ati iyi tọba fi n jẹ ọba mọ, to bẹẹ ti wọn dena de Kabiyesi lọna, ti wọn pa a nipa ifọnna-fọnṣu.
Ṣugbọn awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun lawọn yoo wadii iṣẹlẹ naa, awọn yoo wa awọn to ṣiṣẹ naa jade dandan.