Nitori bi wọn ṣe ti i mọle lọna aitọ, Sunday Igboho pe ijọba ilẹ Bẹnnẹ lẹjọ, o ni afi ki wọn san Miliọnu kan Dọla foun

Nitori bi wọn ṣe ti i mọle lọna aitọ, ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho ti ni gbe ijọba orileede Bẹnnẹ lọ sile-ẹjọ, o si n beere fun miliọnu kan owo dọla, eyi jẹ ọtaleleeedẹgbẹta miliọnu owo ilẹ wa (560m) fun ọjọ kọọkan to ti lo latimọle pẹlu bi wọn ṣe ti i mọle lọna aitọ, ti wọn si tun tẹ ẹtọ rẹ loju mọlẹ lọna ofin.

Ile-ẹjọ adugbo ti wọn n pe ni Community Court of Justice ati ile-ẹjọ awọn ajọ orileede Iwo Oorun Afrika ti wọn n pe ni (ECOWAS), niluu Abuja lo gbe wọn lọ.

Nigba to n sọrọ nipasẹ agbẹjọro rẹ, Tosin Ọjaọmọ, Igboho sọ pe ki ile-ẹjọ kede pe bi ijọba Bẹnnẹ ṣe mu oun, ti wọn ti oun mọle lai nidii lodi si ẹtọ ọmọniyan ti oun ni lati rin sibi to ba wu oun, bẹẹ lo tun lodi si anfaani ti oun ni pe ki wọn gbọ ẹjọ oun lai ṣegbe laarin asiko to yẹ.

O ni ohun ti Igboho n beere fun yii wa ni ibamu labẹ ofin kọkandinlọgọta to ni i ṣe pẹlu igbesẹ lati gbọ ẹjọ Igboho ni kankan lori ẹwọn ti wọn ti i mọ ati lati tu u silẹ.

Agbẹjọro naa waa beere fun pe ki wọn tu Igboho silẹ lai fi ofin tabi ohunkohun ti i nidii pe o gbọdọ ṣe ki eyi too waye, ki wọn si fun un ni iwe irinna rẹ titi igba ti ẹjọ to pe naa yoo fi di gbigbọ.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje, ọdun to kọja ni wọn mu un ni orileede Bẹnnẹ, lasiko to fẹẹ kọja si orileede Germany.

Leave a Reply