Igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, Agbọọla Ajayi, ti ko ọrọ rẹ to sọ lọsẹ to kọja pe oun ko ni i kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, bo tilẹ jẹ pe tikẹẹti ẹgbẹ naa ko ja mọ ọn lọwọ lasiko idibo abẹle ti wọn ṣe laipẹ yii jẹ pẹlu bo ṣe n mura lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party ti Oluṣẹgun Mimiko n dari.
Iroyin to tẹ wa lọwọ bayii ni pe igbakeji gomina naa ti n ṣepade pọ pẹlu ẹgbẹ ọhun, bi ohun gbogbo ba si lọ bo ṣe yẹ, o ṣee ṣe ki ọkunrin naa kede pe oun ti di ọmọ ẹgbẹ naa laipẹ jọjọ. Orukọ ẹgbẹ yii ni yoo si fi dije dupo gomina ti yoo waye ninu oṣu kẹwaa, ọdun yii, l’Ondo.
ALAROYE gbọ pe ọkunrin naa ti n ṣepade pọ pẹlu Oluṣẹgun Mimiko to jẹ gomina Ondo nigba kan, to si tun jẹ oludari ẹgbẹ ZLP lori bi ohun gbogbo yoo ṣe lọ.
Bo tilẹ jẹ pe Akowe iroyin igbakeji gomina naa, Tọpe Ọkẹowo, sọ fun akọroyin wa lọsẹ to kọja ta a ba a sọrọ pe ko si ootọ ninu pe Agbọọla fẹẹ lọ sinu ẹgbẹ oṣelu mi-in, o ni awọn ọta rẹ lo wa nidii eleyii. Ṣugbọn pẹlu bi nnkan ṣe ri yii, ọkunrin naa ti nasẹ sita.
Tẹ o ba gbagbe, lẹyin ibo abẹle ẹgbẹ PPDP to waye lọse to lọ lọhun-un ni Agbọọla ki Mimiko ku oriire, to si sọ pe oun ti gba f’Ọlọrun. Ṣugbọn ọkunrin naa yi oun rẹ pada, o si fi ete awọn oloṣelu han pẹlu bo ṣe n mura lati darapọ mọ ẹgbẹ mi-in, ko le koju Akereolu ti APC, ati Eyitayọ Jẹgẹdẹ lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP ninu eto idibo to n bọ.