Nitori bo ṣe purọ mọ ọga rẹ, adajọ ju Pasitọ Abiọdun sẹwọn ọdun meji l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ile-ẹjọ giga to wa l’Akurẹ ti dajọ ẹwọn ọdun meji fun iranṣẹ Ọlọrun kan, Pasitọ Abiọdun John, lori ẹsun bibura eke ati pipa irọ mọ ọga rẹ, Pasitọ Gbenga Akinbiyi, to jẹ oludasilẹ ijọ Promise Land.

Olujẹjọ ọhun ati ọga agba kan ni Fasiti Adekunle Ajasin to wa l’Akungba Akoko, Ọjọgbọn Lanre Olu Adeyẹmi, ni wọn jọ wọ lọ sile-ẹjọ ẹjọ naa lori ẹsun ọtọọtọ ti wọn fi kan wọn.

Awọn ẹsun bii mẹjọ to da lori lilo ẹrọ ayelujara lati huwa ibi, pipa irọ mọ ọga rẹ atawọn alagba ijọ pe wọn ri olubi atawọn oogun abẹnugọngọ mọ ori pẹpẹ sọọsi, iroyin eke, didun ikooko mọ ẹmi ẹni, pipe ara ẹni loun ti a ko jẹ atawọn mi-in ni wọn ka si olusọaguntan yii lẹsẹ nigba ti igbẹjọ kọkọ bẹrẹ lọdun to kọja.

Koko ẹsun ti wọn fi kan Ọjọgbọn Lanre to n jẹjọ pẹlu rẹ ni ṣiṣe iranwọ fun afurasi naa lori irọ pipa ati iroyin eke to n tan kalẹ nipa ọga rẹ.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, Onidaajọ Bọde Adegbẹhingbe ni ki Ọjọgbọn Lanre maa lọ sile rẹ layọ ati alaafia niwọn igba tawọn olupẹjọ ti kuna ati fidi ẹsun ti wọn fi kan an mulẹ daadaa.

Lori ọrọ ti Pasitọ Abiọdun, Onidaajọ Adegbẹhingbe fagi le meje ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan an, o ni awọn ẹsun wọnyi ko lẹsẹ nilẹ to.

Adajọ ni ki olujẹjọ ọhun lọọ fẹwọn ọdun meji jura fun jijẹbi ẹsun bibura eke ati irọ to pa mọ ọga rẹ nitori pe o ti huwa to lodi labẹ abala kejidinlọgọfa ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo.

Onidaajọ Adegbẹhingbe ni ki ojisẹ Ọlọrun naa ṣi wa latimọle awọn ọlọpaa titi ti ero yoo fi dinku ninu ọgba ẹwọn ti wọn n mu un lọ latari arun Korona to wa nita.

 

Leave a Reply