Nitori Buruji Kaṣamu, Fayoṣe sọrọ s’Ọbasanjọ, o ni ki baba yee ṣe bii angẹli jare

Gomina Ekiti nigba kan, Ọgbẹni Peter Ayọdele Fayoṣe, ti fibinu sọrọ si aarẹ ana, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ. O ni o ti mọ baba naa lara ko maa ṣe bii angẹli, bẹẹ ki i ṣe angẹli, nitori ọwọ oun paapaa ko mọ rara.

Lori ẹrọ ayelujara rẹ, twitter, nibẹ ni Fayoṣe ti n kẹdun iku to pa Ẹṣọ Jinadu, to si ba gbogbo ẹbi rẹ daro, nitori o ni eeyan daadaa ni Buruji Kaṣamu i ṣe. Nigba naa lo wa sọrọ si Ọbasanjọ pe ohun to sọ lẹyin iku Kaṣamu ki i se ọrọ to dara, paapaa nigba to mọ pe ọkunrin naa ko si laye mọ lati le gbeja ara rẹ. O ni Ọbasanjọ ko le bura pe igba kan ko si ti oun ati Kaṣamu sun mọ ara awọn, to si jẹ gbogbo ohun ti Kaṣamu n ṣe nigba naa, pẹlu aṣẹ ati atilẹyin oun Ọbasanjọ ni.

Ọbasanjo lo ti kọkọ sọrọ ninu lẹta ibanikẹdun ti oun kọ pe Kaṣamu lo ọgbọn oṣelu ati ete lati fi bọ lọwọ awọn ọlọpaa aye, ṣugbọn ko ribi bọ lọwọ awọn ọlọpaa ọrun, pe gbogbo ohun tawọn oloṣelu ba n ṣe ki wọn ranti iku, nitori ko si ibi ti wọn yoo ri ibi sa gba lọ. Ọrọ yii lo bi Fayoṣe ninu.

O ni Ọbasanjọ fẹran lati maa pe ara rẹ ni angẹli loju gbogbo aye, bii ẹni ti ọwọ rẹ mọ ju lọ, bẹẹ ọwọ oun naa ko mọ rara. Gomina ana naa ni gbogbo ọmọ Naijiria yoo maa woye igbẹyin baba yii funra rẹ, nitori ohun to gbẹyin Kaṣamu ni yoo gbẹyin oun naa, awọn araaye yoo si sọ ohun ti oun naa gbe ile aye ṣe bo ba ku tan.

3 thoughts on “Nitori Buruji Kaṣamu, Fayoṣe sọrọ s’Ọbasanjọ, o ni ki baba yee ṣe bii angẹli jare

Leave a Reply