Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ẹṣọ Amọtẹkun, ẹka tilu Ondo, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo, ni wọn ti fẹsun kan pe wọn lọwọ ninu bi wọn ṣe fiya jẹ ọdọmọkunrin ẹni ọdun mẹrinla kan, Ayọmide, titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ.
Iṣẹlẹ yii la gbọ pe o waye lagbegbe Ògbòǹkowò, Odojọmu, niluu Ondo, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinla, oṣu Karun-un, ọdun 2023 ta a wa yii.
ALAROYE gbọ pe ọmọkunrin ọhun ni wọn lo wa ni kilaasi kin-in-ni agba nile-iwe girama kan niluu Ondo.
Iyaale iya rẹ kan tawọn eeyan mọ si Mary ni wọn lo gbe irẹsi ṣiṣe le ọmọ naa lori pe ko kiri lọ lọjọ iṣẹlẹ naa, niwọn igba ti iya to bi i lọmọ pẹlu baba rẹ ti kọ ara wọn silẹ.
Lẹyin to pada de lati awọn ibi to kiri lọ ni wọn obinrin yii ki i mọlẹ, to si lu u lalubami lori ẹsun pe owo ọja to gbe jade ko pe, o ni owo naa din ẹẹdẹgbẹta Naira.
Wọn lo kọkọ beere lọwọ rẹ bi ọrọ owo to sọnu naa ṣe jẹ lọwọ ọmọ naa. A gbọ pe ṣiṣẹ ti Ayọmide ṣẹ kanlẹ pe oun ko mọ ohunkohun nipa owo to dawati ọhun lo bi obinrin naa ninu to fi bẹrẹ si i lu u bii ẹni lu baara pẹlu ẹgba, to si ni o gbọdọ jẹwọ ibi to fi owo oun si.
Nigba to lu ọmọkunrin ọhun tan ti ko tẹ ẹ lọrun ni wọn lo tun fi awọn iya mi-in jẹ ẹ fun bii ọpọlọpọ wakati. A gbọ pe ẹyin eti rẹ ni gbogbo ẹbẹ ti awọn araadugbo n bẹ ẹ lọjọ naa pe ko fi ọmọ naa silẹ n bọ si.
Lẹyin-o-rẹyin ni wọn lo ṣẹṣẹ waa fa ọmọ orogun rẹ ọhun le awọn ẹṣọ Amọtẹkun ilu Ondo lọwọ, nibi ti wọn tun ti fiya jẹ ẹ titi to fi daku mọ wọn lọwọ.
ALAROYE gbọ pe wọn sare gbe ọmọ naa lọ sileewosan ijọba to wa niluu Ondo, fun itọju, ibẹ ni wọn lọmọ ọhun pada ku si lẹyin wakati diẹ ti wọn gbe e debẹ.
Nigba ta a pe Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, lati fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, o ṣalaye fun akọroyin wa pe ko pe awọn ẹṣọ Amọtẹkun funra wọn, niwọn igba to jẹ awọn ni wọn fẹsun kan.
Igba meji ọtọọtọ la pe Akọgun Adetunji Adelẹyẹ to jẹ adari ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo, ṣugbọn ti ko gbe e, bẹẹ ni ko ti i pe wa pada titi ta a fi kọ iroyin yii tan.