Nitori EFCC, awọn ọdọ fẹhonu han l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọgọọrọ awọn ọdọ ni wọn jade lati fẹhonu han ta ko bi ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati ṣiṣe owo baṣubaṣu lorilẹ-ede yii, (EFCC), ṣe ya bo ile-ijo kan niluu l’Akurẹ, nipinlẹ Ondo, lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa yii, ti wọn si fi pampẹ ofin gbe awọn eeyan bii mẹtadinlaaadoje (127) lọ.

Awọn olufẹhonu-han ọhun ni wọn di ọna marosẹ to gba ọfiisi gomina to wa ni Alagbaka, kọja pa, leyii to mu ko ṣoro fawọn awakọ to rin si asiko iṣẹlẹ naa lati raaye kọja fun ọpọ wakati.

Ọkan ninu awọn olufẹhonu-han ọhun, Ọgbẹni Oluwaṣeun Ogunmọla, ninu ọrọ to b’awọn oniroyin sọ ni bi ajọ EFCC ṣe lọọ ya bo awọn ẹni ẹlẹni laarin oru, nibi ti wọn ti n jaye ori wọn lọwọ, ta ko ofin to de wọn pe wọn ko gbọdọ lọọ maa ko awọn eeyan loru mọ.

O ni awọn jade lati fi aidunnu awọn han si igbesẹ naa, ti awọn si fẹ ki ajọ EFCC tete tu gbogbo awọn ti wọn ko naa silẹ lẹyẹ-o-sọka, lai fẹẹ mọ iru ẹsun yoowu ti wọn ibaa fi kan wọn.

Ẹlomi-in to tun ba awọn oniroyin sọrọ, Tobi Akinnubi, ni ko sofin to de ẹnikẹni lati ma ṣe lo foonu olowo nla, kọmputa agbeletan tabi ọkọ ayọkẹlẹ, o ni asiko ti to kí ìjọba apapọ tete ba ajọ EFCC sọrọ lori ohun to le da rogbodiyan silẹ ti wọn rawọ le.

Ninu ipade kan ti Gomina ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Lucky Orimisan Ayedatiwa, ṣe pẹlu awọn onile-itura ọhun lọfiisi ijọba to wa l’Akurẹ, lẹyin iṣẹlẹ ọhun ni oun gbagbọ pe o lohun tawọn ẹṣọ alaabo naa ri ki wọn too gbe igbesẹ ti wọn gbe, nitori awọn agba bọ, wọn ni, ‘ti ko ba nidii, ẹ̀ṣẹ́ ki i deedee ṣẹ.’

Gomina kaaanu pẹlu awọn onile-itura ọhun lori awọn nnkan ini wọn to ṣee ṣe ko bajẹ lasiko tawọn EFCC fi waa ṣiṣẹ wọn, o ni oun ti n ba awọn tọrọọ kan sọrọ lati yanju ọrọ naa nitunbi inubi.

 

Leave a Reply