Nitori ẹgunjẹ, ọlọpaa fi idi ibọn gba Taiwo lori, niyẹn ba daku, ko ti i ji saye o

Florence Babasola, Osogbo

Ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun ni Ayọmide Taiwo wa bayii latari bi ọkunrin ọlọpaa kan ṣe fi idi ibọn gba a lori niluu Ilahun nijọba ibilẹ Ibokun nitori ẹgunjẹ aadọta naira pere.

Ọdun Ileya la gbọ pe Ayọmide, ẹni ogun ọdun, wa ṣe niluu Iragbiji, oun ati ọrẹ rẹ, Wasiu Ọladimeji si n pada sibugbe wọn, Ọwẹna, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Ayọmide, ẹni to jẹ aranṣọ (tailor) lo wa ọkada ti wọn n gbe lọ, Wasiu si joko lẹyin rẹ. Gẹgẹ bi Wasiu ṣe sọ, ọna bii mẹrin ni wọn ti pade awọn ọlọpaa ti wọn si n fun wọn lowo.

Ṣugbọn nigba ti awọn ọlọpaa ti Ilahun da wọn duro, Ayọmide tọwọ bọ apo lati mu aadọta naira jade, bi ọkan lara awọn ọlọpaa naa, ẹni ti wọn sọ pe o ti muti yo, ṣe ri i pe beeli ẹgbẹrun lọna aadọta naira wa ninu apo rẹ bayii, lo fa ibinu yọ.

Wasiu ṣalaye pe, “Bi ọlọpaa yẹn ṣe ri owo yii lo jan idi ibọn mọ Ayọmide lori, awa mejeeji si ṣubu latori ọkada. Bayii lẹjẹ bẹrẹ si i jade ni imu, ẹnu ati eti Ayọmide.

“Awọn ọlọpaa to ku nibẹ sa lọ, ṣugbọn awọn eeyan ti wọn wa nitosi ibẹ ko jẹ ki ọlọpaa to gba Ayọmide nidi ibọn raaye sa lọ. Ibẹ la wa ti ọlọpaa kan to n bọ lati ibiiṣẹ ti ri wa, oun lo fi mọto rẹ gbe Taiwo lọ sileewosan LAUTECH niluu Oṣogbo.

“Titi di bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, Ayọmide o ti i pada ji saye o, bẹẹ ni a ko ri foonu rẹ pẹlu paaki ẹgbẹrun lọna aadọta naira to wa ninu apo rẹ”.

Leave a Reply