Nitori ẹjọ ti adajọ da fun un, Akala fo windo jade ni kootu, lo ba fere ge e

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ṣe lọrọ ọhun da bii ere ori-itage, nigba ti ọkunrin afurasi kan ti wọn porukọ rẹ ni Ṣẹgun Akala, sare bẹ jade lati oju fereṣe ile-ẹjọ to ti n jẹjọ lọwọ niluu Odigbo, ti i ṣe ibujokoo ijọba ibilẹ Odigbo, pẹlu ṣẹkẹṣẹkẹ lọwọ, lẹyin ti adajọ kootu ọhun ni ki wọn ṣi lọọ fi í pamọ sọgba ẹwọn na titi digba ti wọn yoo fi ṣeto beeli rẹ.

Akala ni wọn wọ wa sile-ẹjọ ọhun lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, lori ẹsun ole jija.

Olujẹjọ naa ni wọn lo lọ si agbegbe kan loju ọna Aipọn, nitosi Odigbo, lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023, nibi to ti ji ṣeeni nla ẹrọ ti wọn fi n lagi, eyi ti owo rẹ to bii ẹgbẹrun lọna ojilelọọọdunrun din mẹrin Naira (#336, 000,00). Ẹru to ji ọhun ni wọn lo jẹ ti ẹnikan torukọ rẹ n jẹ Akintan Akintade.

Ẹsun ọhun ni wọn lo ta ko abala irinwo din mẹwaa ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.

Lẹyin ti Akala ti loun ko jẹbi ẹsun ole jija ti wọn fi kan an ni agbefọba bẹbẹ fun sisun igbẹjọ siwaju, ki oun le raaye ṣe ayẹwo finnifinni si iwe ẹsun ti wọn fi kan olujẹjọ.

Agbejọro rẹ, Ọgbẹni Rufus Ọmọtayọ, bẹbẹ fun gbigba beeli onibaara rẹ, o ni ofin faaye beeli gbigba silẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ D. O. Ogunfuyi, ni oun gba ki wọn gba beeli rẹ pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan Naira ati awọn meji ti yoo duro fun un ni iye owo kan naa.

Adajọ ọhun waa paṣẹ pe ki wọn ṣi lọọ fi olujẹjọ naa pamọ si ọgba ẹwọn to wa l’Okitipupa, titi ti yoo fi ri ọrọ beeli ti wọn fun un yanju.

Eyi ni Akala gbọ to fi gbọn ara jigi, to si fo gija gba oju ferese kootu ọhun sa jade pẹlu ṣẹkẹṣẹkẹ lọwọ rẹ.

Wahala diẹ kọ lawọn ẹṣọ alaabo kootu ọhun ṣe ki wọn too ṣẹṣẹ ri ọkunrin naa mu pada ninu igbo to lọọ fara pamọ si.

Leave a Reply