Nitori ere asapajude, ajọ ẹsọ oju popo mu mọto akero marundinlogoji

Jide Alabi

Ileeṣẹ ijọba to n mojuto irinna ọkọ loju popo (FRSC), Ọgbẹni Oluṣẹgun Ogungbemide, ti sọ pe awọn mọto akero marundinlogoji (35) lọwọ awọn ti ba bayii, nitori ti awọn to ni wọn ko tẹle aṣẹ ijọba nipa lilo ẹrọ to le din ere asapajude ku.

Ogungbemide ṣalaye ọrọ yii  fawọn oniroyin lẹyin ipade to ṣe pẹlu awọn onimoto ti wọn n na Eko si Ibadan. O ni o ṣe pataki fun wọn lati maa lo ẹrọ ti yoo maa ṣadinku ere asapajude to wọpọ laarin awọn onimọto ero.

Ogungbemide fi kun ọrọ ẹ pe aṣẹ ti ajọ naa n tẹle bayii ni i ṣe pelu ohun ti ọga agba ajọ to n ri si irinna oju popo, Dokita Boboye Oyeyẹmi, sọ, paapaa lori akiyesi bi ọpọ ẹmi ṣe n ṣofo latari ere isakusa lasiko ayẹyẹ ọdun.

O ni, “A ko ni i gbe mọto yẹn fawọn to ni wọn ti wọn ko ba fi ẹrọ ti yoo maa din ere asapajude ku si i, koda, ki wọn sanwo itanran fun ijọba. O ṣe pataki ki gbogbo mọto akero ni in, bẹẹ la o ni i faaye gba aitẹle ofin ọhun latọwọ ẹnikẹni.”

Bakan naa lo rọ awọn onimọto lati ṣe pẹlẹ, ki wọn si tun pa ofin ati ilana itankalẹ àrùn koronafairọọsi mọ dáadáa lẹnu iṣẹ wọn.

Leave a Reply