Nitori esi idibo, awọn obinrin bẹ alalẹ lọwẹ ni Kogi  

 Adegoke Adewumi

Awọn obinrin kan lati Aarin Gbungbun ipinlẹ Kogi, ti fẹhonu wọn han nitori abajade esi idibo ileegbimọ aṣofin agba ti wọn di nipinlẹ naa ni ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii.

Awọn obinrin naa ti wọn pọ niye ni wọn wọ aṣọ funfun, ti wọn si mu imọ ọpẹ lọwọ, bẹẹ ni wọn to lọwọọwọ lọ si inu igbo kan ti awọn kan sọ pe idi oriṣa kan ni wọn lọ.

Lẹyin ti wọn kuro ninu igbo yii ni wọn tun pada wa si igboro, ti wọn si n kọrin.

Ninu fidio awọn obinrin to mura bii oloriṣa naa to n ja ran-in lori ayelujara ni awọn eeyan naa ti rọ ajọ eleto idibo lati ṣe ẹtọ to yẹ lori esi idibo agbegbe naa, eyi ti wọn ni awọn di fun obinrin oloṣelu to gbajumọ nipinlẹ Kogi nni, Natasha Akpoti Uduaghan. Wọn ni ki ajọ eleto idibo kede obinrin naa bii ẹni to wọle ibo awọn aṣofin agba.

ALAROYE gbọ pe aṣa ki awọn obinrin wọ aṣọ funfun, ki wọn si ja imọ ọpẹ yii maa n waye lati pe awọn alalẹ tabi ogun nigbakugba ti wọn ba woye pe awọn kan rẹ awọn jẹ.

Tẹ o ba gbagbe, Sadiku Ohere, ti ẹgbẹ oṣelu APC ni ajọ eleto idibo kede pe o jawe olubori ninu ibo ileegbimọ aṣofin agba adugbo naa. Ṣugbọn oludije sipo naa ninu ẹgbẹ PDP, Natasha, ti ni oun ko gba ibo naa wọle nitori pe o kun fun ọkan-o-jọkan eru, to si n ke si ajọ eleto idibo lati fagi le e. Ṣugbọn INEC pada kede Sadiku gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori.

Leave a Reply