Nitori ẹsun agbere, Ọlatunji gun iyawo ẹ pa l’Owode-Ẹgba

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

 

Awọn atẹjiṣẹ to jọ mọ ọrọ ifẹ ti baale ile kan, Ọgbẹni Ṣobọla Ọlatunji, loun n ri lori foonu iyawo oun, to si jẹ pe ale lo n fi wọn ranṣẹ si i lo fa a toun pẹlu iyawo naa, Mọmudat Ṣobọla, fi bẹrẹ ija lọjọ kẹtala, oṣu keji yii, n lọkọ ba fi ọbẹ gun iyawo lẹyin, lobinrin naa ba dagbere faye.

Ogun ọdún sẹyin lawọn eeyan yii ti fẹra wọn gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe wi, wọn si ti bimọ mẹta funra wọn.

Lori iku Mọmudat yii, baba rẹ, Alaaji Ambali Yinusa, lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Owode-Ẹ̀gbá, pe ọmọ oun ati ọkọ rẹ ja, ọkunrin naa si ti gun un lọbẹ lẹyin.

Awọn ọlọpaa sare debẹ, wọn mu Ọlatunji, ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta wọn si gbe iyawo ẹ lọ sọsibitu.

Ṣugbọn nibi ti wọn ti n tọju ẹ lọwọ lo ti ku. Ẹni ọdun mejidinlogoji ni Mọmudat to doloogbe yii.

Nigba to n ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fawọn ọlọpaa, Olatunji sọ pe oun fura siyawo oun pe o n yan ale, nítorí awọn atẹjiṣẹ toun maa n ri lori foonu rẹ, to ni i ṣe pẹlu ifẹ si ni.

O ni lọjọ Satide ti wahala ṣẹlẹ yii, oun ko o loju pe o n yan ale ni, oun beere lọwọ ẹ pato, ọrọ naa lo dija, to di pe iku lo pada ja si.

Mọsuari ni Mọmudat wa bayii, lọsibitu Olabisi Ọnabanjọ to wa ni Ṣagamu. Ọkọ rẹ wa lẹka ti wọn ti n gbọ ẹjọ awọn apaayan, ibẹ ni yoo gba dele-ẹjọ bawọn ọlọpaa ṣe wi.

Leave a Reply