Nitori ẹsun ibanilorukọjẹ, PDP tọrọ aforiji lọwọ gomina ati INEC ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Lẹyin ti Kọmisanna fun ajọ eleto idibo nilẹ yii, ẹka ti ipinlẹ Kwara (REC), Malam Garba Attahiru Madami, ti fun ẹgbẹ oṣelu PDP ni wakati mejidinlaaadọta ko tọrọ aforiji lori ẹsun ibanilorukọjẹ to fi kan ajọ naa ati Gomina Abdulrazaq, Alukoro ẹgbẹ oṣelu naa, Ọmọọba Tunji Moronfoye, ti tọrọ aforiji lọwọ Gomina Abdulrazaq ati ajọ INEC.

Tẹ o ba gbagbe ṣaaju ni Madami ti kilọ fun ẹgbẹ oṣelu PDP, to si fun wọn ni gbedeke ọjọ lati tọrọ aforiji lẹyin ti Alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP, sọ pe ajọ INEC ni Kwara ati Gomina Abdulrazaq fẹẹ lẹdi apo pọ ki ẹgbẹ oṣelu APC, le jawe olubori nibi eto idibo apapọ ọdun 2023, ti oun si ri i ti Abdulrazaq, gbe ọọdunrun miliọnu Naira le Madami lọwọ lẹyin ipade kan ti wọn ṣe niluu Ilọrin.
Nigba ti Madami n ba awọn oniroyin sọrọ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, niluu Ilọrin, o ṣàlàyé pe orukọ rere toun ti n gbe gẹgẹ lati ọdun pipẹ ni ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ naa fẹẹ bajẹ lai besu-bẹgba, ti wọn si parọ banta-banta pe oun ti gba miliọnu lọna ọọdunrun Naira (300milion) lọwọ ẹgbẹ to n ṣejọba lọwọ ni Kwara, All Progressives Congress (APC), ki wọn le feru wọle nibi idibo apapọ ọdun 2023.
O tẹsiwaju pe irọ to jinna si ootọ ni, ati pe ọrọ ibanilorukọjẹ ni, fun idi eyi, oun fun ẹgbẹ oṣelu naa ni wakati mejidinlaaadọta pere lati lọ si awọn ileeṣẹ iwe iroyin ati awọn ileeṣẹ redio ati tẹlifiṣan, ki wọn tọrọ aforiji tabi ki wọn foju ba ile-ẹjọ laipẹ jọjọ. O fi kun un pe lati nnkan bii ogoji ọdun ni orukọ naa ti wa, toun si n gbe e gẹgẹ sugbọn ti ẹgbẹ oṣelu PDP fẹ ba orukọ naa jẹ mọ oun lọwọ.

Ni bayii Alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP ni Kwara, Ọmọọba Tunji Moronfoye, ti ko ọrọ naa jẹ, to si tọrọ aforiji lọwọ gomina ati ajọ eleto idibo.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: